Saturday, 15 August 2015

Cake

(V/IṢ): dé. fi nnkan tí ó nípọn díẹ̀  dé nnkan tàbí ẹni kan tí nnkan tí a fi dé nnkan yìí yóò sì wá gbẹ. The men’s shoes were caked with mud. Àbàtà gbẹ mọ́ bàtà àwọn ọkùnrin náà.
 (N/OR): (i) oúnjẹ aládùn kan tí a n fi àpapọ̀ fúláwà, súgà, ẹyin àti ọ̀rá ṣe. Would you like a piece of my birthday cake? Ṣé kí n fún ọ ní díẹ̀ nínú kéèkì ọjọ́ ìbí mi?
(ii) ìrísí. nnkan pẹlẹbẹ kékeré tí a ṣe nípa títẹ nnkan tí kò le mọ́ ara wọn. He gave me a cake of soap. Ó fún mi ní ọsẹ pẹlẹbẹ kan.
cake walk (N/OR): nnkan tí ó rọrun láti rí tàbí, nínú ìdíje, kí ẹni kan gbà pé wọ́n ti ṣẹ́gun òun láìjanpata rárá. The last football match was a cake walk for our team. Pẹ̀lú ìrọ̀rùn ni àwọn agbábọ́ọ̀lu wa fi borí níbi ìdíje tí ó kọjá.

No comments:

Post a Comment