Friday, 24 July 2015

shoulder





(i) (N/OR) :ejìká  The boy placed the load on his shoulder. Ọmọ náà gbé ẹrù náà lé èjìká rẹ̀
(ii) (N/OR): ẹran tí ó jẹ́ pé apá òkè iwájú ẹsẹ̀ ẹranko wà níbẹ̀. I bought a shoulder of goat. Mo ra apá òkè iwájú ẹsẹ̀ ewúrẹ́.
(iii) (V/IṢ): gbà  pé ẹni náà ni nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ kan gbọ̀gbọ̀n. The teachers alone cannot shoulder the blame for the student’s truancy at school. A kò lè dá ẹ̀bi ìsaǹsá ọmọnáà  ní ilé-ẹ̀kọ́ ru àwọn olùkọ́ nìkan.
(iv) (V/IṢ): gbé nǹkan lé èjìká. Shouldering her piece of baggage, he left for his town. Lèyìn tí ó ti gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká tan, ó gba ọ̀nà ìlú rẹ̀ lọ.
(v) shoulder bag (N/OR): báàgì tí a máa ń fi ìkọ́ rẹ̀ kọ́ èjìká
(vi) shoulder bone (scapular) (N/OR): eegun kan tí ó wà ní ẹ̀yìn wa ní abẹ́ èjìká tí ó ń jẹ́ kí lílọ síwáju àti  lílọ sẹ́yìn apá pọ̀ sí i.
(vii) -shouldered (suffix): àfòmọ́ ẹ̀yin. He is broad-shouldered. Èjìká rẹ̀ fẹ̀. (viii) shoulder-length (adj/AJ): Your hair is shoulder-length. Irun rẹ gùn dé èjìká.
(ix) shoulder pad (N/OR): nǹkan bí òṣùká tí a máań fi sí abẹ́ aṣọ ní ibi èjìka kí ó lè ga sí i tàbí kí ó lè dára sí i
(x) shoulders (N/OR) (1) òkè apá. He is about five feet tall with narrow shoulders. Ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún. Èjìká rẹ̀ kò fẹ̀ (2) apá kan aṣọ tí ènìyàn wọ̀n tí ó bo èjìká. The shoulders are tight. Èjìká aṣọ náà fún.
(xi) shoulders (N/OR): ẹrù. The responsibility of the problem rests on your shoulders. Èjìká (ọrùn) rẹ ni wàhálà ọ̀rọ̀ náà wà. (xii) shoulder strap (N/OR): Ọwọ́ báàgì tí a máa ń gbé kọ́ èjìká.

No comments:

Post a Comment