Wednesday, 1 July 2015

ÌPADÀBỌ̀ AÁFÍRIKÀ




Gbogbo àwa èèyàn dúdú
Gbogbo wa ló ń sunkún kíkorò
Ẹkún àsun-ùn dabọ̀
Fún ọ, ìwọ Aáfíríkà
Tí wọ́n gbà lọ́wọ́ awọn babaa babaa wa                                           5
Nígbà tójú ò ì tíì là tó yìí

Mo ní o padà bọ̀
Dákun padà bọ̀, ilẹ̀ Aáfíríkà
Táwọn Èèbó gba lọ́wọ́ọ wa
Nígbà tójú sì dúdú                            10

Mo ní o padà bọ̀
Dákun padà bọ̀ ilẹ̀ Aáfírikà
Táwọn Potogí sọ dẹrú
Nígbà ojú sì dúdú

Mo ní o padà bọ̀                     15
Dákun padà bọ̀, ilẹ̀ Aáfíríkà
Tá a tà látọwọ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀
Nígbà ojú sì dúdú

Mo ní o padà bọ̀
Dákun padà bọ̀, ilẹ̀ Aáfíríkà            20
Kí gbogbo ìyàa wa kọjá
Kí gbogbo wa dòmìnira

Mo ní o padà bọ̀
Dákun padà bọ̀ ilè aáfíríkà
Òmìnira yìí ò tíì kárí                       25
Wòyà tó sì ń jẹ wọ́n níhà ibì kan

Mo ní o pada bọ̀
Dákun padà bọ̀, ilẹ̀ Aáfíríkà
Òmìnira òṣèlú yìí ò tí ì tó
A tún ń fẹ́ tọrọ̀ ajé pẹ̀lú       30

Mo ní o padà bọ̀
Dákun padà bọ, ilẹ̀ Aáfíríkà
Tó o bá fi tọrọ̀ ajé kún un tán
Kó o wáá fi tèdè kún un pẹ̀lú

Mo ní o padà bọ̀                    35
Dákun padà bọ̀, ilẹ̀ Aáfíríkà
Tó o bá ṣe gbogbo èyí tán
Kó o wáá fìṣọ̀kan sáàárín-in wa.

No comments:

Post a Comment