UNESCO, Ajọ Ìgbìmọ̀ Àgbáyé fún Ẹ̀kọ́,
Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìṣẹ̀ṣe pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ADEA, Ẹgbẹ́
fún Ìdàgbàsókè Ẹ̀kọ́ ní Aáfíríkà àti Michel Lafon Education gbé
àwọn ìwé kan jáde ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ètò ẹ̀kọ́ ilẹ̀
Aáfíríkà. Àkọlé àwọn ìwé náà ni: Bouba àti Zaza Ṣokùnfà Àlàáfíà, Bouba àti Zaza Mọ Ìwà fún
Oníwà, Bouba àti Zaza Gbé Ẹ̀kọ́ Ọmọbìnrin Lárugẹ, Bouba àti Zaza
Bọ̀wọ̀ fún Omi, Bouba àti Zaza Kọ́ nípa Àìfẹ̀mí Wéwu Lóju Pópó.
Àwọn ìwé wọn mìíràn tí ó tún ń bọ̀ ni: Bouba àti Zaza Kọ́ nípa Ìmọ́tótó, Bouba àti Zaza Kò Gba ti
Oògùn Olóró, Bouba àti Zaza Dáàbo bo Ara Wọn Lówọ́ Ibà, Bouba àti
Zaza Ṣe Àwárí Ibùgbé Wọn ní Ilẹ̀ Ayé àti Bouba àti Zaza ń Sọ bí Wọ́n ti ń Jẹun. Wọ́n kọ àwọn
ìwé wọ̀nyí pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ẹ̀kọ́ ń Fún Ọjọ́ Iwájú Ọmọdé
ní Ìdánilójú.
No comments:
Post a Comment