Ǹjẹ́ tó o ba fẹ́ lóbìnrin ọ̀rẹ́ẹ
wa,
Ọ̀rọ̀ gbàdúà
Tori ọ̀rọ̀ kan ṣẹ̀ nígbà ìṣẹ̀ǹbáyé
To jóhun to kọni lóminu to gbọgbọn
jọjọ,
Ọkunrin ọ̀gágun kan lo fáya ti ò
bọ̀pẹ̀lẹ̀ wò 5
T’ayá ijọ́wo níhìn-ín wáá dẹni tó ń kó
bani
Kédùmare jọ̀wọ́ fún wa lóbinrin ẹni,
aya àtàtà,
Ká má ṣe gbákóbáni sílé ka lá a fáya
Ọ̀gá yii ń toju ogun bọ̀ tòun tọ̀rẹ́
ẹ̀
Pẹ̀kí mo ko’re ni wọ́n ko awọn àgbà
mẹ́ta 10
Ṣọ́rọ̀ àwọn àgbà si maa ń ṣẹ tẹ́lẹ̀ níṣẹ̀ǹbáyé.
Ríríi wọ́n ri wọ́n làwọ̀n èníyán
móhùn sẹnu
Wọ́n ni, “Mọ́kùú, àbí wọ́n ti ń pè
ọ́ ri?”
Ẹni à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni wọ́n ń
fọ̀ sí t’ó ò bá mọ̀
Wọ́n ní “Kaabiyesi, olori ogun lo jẹ́,
o máa dọba” 15
Ọ̀rọ̀ yìí gbèrò, o fa háà dani
Nitori ọba ti ń bẹ lóyè ò kú, bẹ́ẹ̀
ni, kò ṣàìsàn
“Bi n ó ṣe jọba yìí yóó ṣojú gbogbo
wá”
Bayii ni Mọ́kùú sọ to dára le nì
tìrẹ̀
Ṣùgbọ́n wọ́n ni, ‘Ibi ti a ti ń wo
alaáìsán la ń wora ẹni 20
Ẹni dákẹ́ ti ẹ̀ náà a bá a dakẹ́,”
kìí ṣèèwọ̀
Nnáà lọ̀rẹ́ Mọ́kùú, eyi ti ń jẹ́
Jọjọ
Lo ni k’awọn àgbà yẹ oun lọ́wọ́ kan
ìbò wò
Ni ọ̀rọ̀ di fàà ńlẹ́
N ló mórin bọnu to ń ké tantan 25
Pé “Ire ti n ó ní ń kọ́ ni mo wí,
Oju àgbà mò ń wò.
Ireè mi gbogbo lọ́wọ́ àgbà
Aṣọ tí n o ni ń kọ́ ni mo wi,
Oju àgbà mò ń wò 30
Ire mi gbogbo lọ́wọ́ àgbà,
Ire gbogbo tí n ó ni ń kọ́ ni mo
wi,
Oju àgbà mò ń wò.
Ire mi gbogbo lọ́wọ́ àgbà.
Ẹyin eníyán, ẹ̀yin ènìyàn 35
Kẹ tètè wa ba mi dámọ̀ràn
Bíwá o ti rí fun mi o.”
Awọn àgbà náà ò kúkú fìkan pe méjì
Wọ́n ni “Bi Dàda ò lè jà
Aburo ti
ń bẹ lẹ́yin rẹ̀ gbóju jọjọ 40
Wọ́n ní ‘o ò níí jọba
Ṣùgbọ́n tìrandíran-an rẹ lọbaá ṣe.”
Bayii lawọn àgbà sọ mọ
Tí wọ́n pòórá, ti wọ́n dàwá tì
Nnáà làwọn ọ̀rẹ́ meji ba file ṣe
lílọ́ 45
Wọ́n
dele, ọba ń file potí, o ń fonà rokà
Nítori ogun won lo, ogun gidi ni í ṣe
Ìjàa won jà lo ṣèjà àtàtà
Loba
ba fi pèrò pọ̀ to kúkú selérí
Poun á bẹ Mọ́kùú wò délédélé 50
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀gágun pàtàkì, akọ ninu
ogun.
Mọ́kùú délé, o fìròyìn tétí aya rẹ̀
lọ́ọ̀dẹ̀
K’Oluwa ma f’ayaabú fun wa fẹ́, ẹ
ṣàmín ẹ̀
Aya ni, “Kò si ṣíṣe kò ṣáìṣe pípa
lo yọba”
“Kó fipòólè f’ólòó ẹlẹ́jẹ̀ tútù 55
Kọ́ba wàjà ká fẹ́lòmíìn jọba.”
Ṣó kúkú ti mọ̀ pọ́rọ̀ ọba míìn ò
le kọja Mọ́kùú
À bẹ́ ẹ̀ rímọ̀ràn ìyàwó oníràdà
Aya burúkú tí í mú’ni ṣebi
Mọ́kùú gbọ́, o gba tìyàwó ẹ̀
àfẹ́-sílé 60
O pèrò pọ̀, o fi tikú ṣe tọba
Ìránṣẹ́ ọba t’o kọ háà láfẹ̀mọ́jú
Lo ni kẹ́nu ẹ̀ ya dépàkọ́ láìṣẹ̀
tì
Kò pẹ́ náà, kò jìnà tí wọ́n fi Mọ́kùú
joyè
Wọ́n gbadé lé e lórí ń ló fi dọba 65
Ó joye tan ìrònú ò tán, ìrònú ò kúrò
Ó rántí óhun ayé wi, o ranti ohun éníyán
sọ
Pe Jọjọ ò ní í joyè ṣùgbọ̀n ọmọ ẹ̀
ni yóó jàrólé,
Àṣé tọ́jọ́ bá ro tán, adìyẹ a máa
jẹ̀fun ara wọn,
Ọdẹ a máa pọdẹ, kò léèwọ̀ 70.
Ògún a máa pọkọ sẹ́yìnkùnlé
A pàlè sídìí ààrò
A paya sìta gbangba
Bayii náà ni Mọ́kùú ránṣẹ́ sawọn
panipani
Pe wọn ó gbóríi Jọjọ wá tọmọtọmọ 75
Ki
wọ́n o pa erú ikú tòun tèso inu rẹ̀
Ṣàwon wọ̀nyi ò moju to fọ́ yàtọ̀
séyìí tó ń ṣedin
Awọn lolórí ńlá, awọn lalátàrí
gèlèmọ̀
Wọ́n múrìn àjò pọ̀n, wọ́n lọ̀ dọdẹ
Jọjọ
Wọ́n dọdọ Jọjọ bi ẹni dọdẹ eku 80
Wọn sẹni ẹlẹ́ni dohun a ń fihun pa
Ṣugbọn ọba ń bẹ loke ti ò nii jẹ́
wọn ó pa Jọjọ lápàarun
Jọjọ la rí mú, ọmọ feré gé e
Ọ̀rọ̀ yii ṣẹ̀ẹ̀ wa ń dọ̀ràn, o ń
di kàyéfi
Ọba tun gbádé orí, ó lọ fi pàdé wọn 85
Awọn ìyá mi ìyá òsòròngà, awọn ayé,
Àwọn tí ń tinú jẹran ti ń tẹ̀dọ̀ jọkàn
Wọn a tìdí jòróòro
“Ǹjẹ́ bá wo la o ti ṣe ti ọmọ
Jọjọ tó sá?”
“A á ti í ṣe é tá à á fi í tẹ́, ẹyin
iyá mi àgbà lọrùn-un?” 90
Ṣé ẹ ń fọkàn sítàn mi ẹ̀yin èyàn
mi?
Ṣé è ń fọkàn sítàn mi, ẹ̀yin èèyàn
àtàtà?
Awọn àgbà tun fọkàn Mọ́kùú balẹ̀
Pé kó má mikan, kó ma kọminú,
Gìrì àparò lásan ni, kò séwu lóko 95
Ẹni yóó wodò lominú ń ko, ẹ̀rù ò
bodò
Wọ́n ló dijọ́ igi ba ṣídìí tó ń rìn
bi èèyàn
Wọ́n ló dijọ a bímọ ti ò tabẹ́ ìyá
jáde
Nnáà nikú ayé tó lè pa Mọ́kùú.
Ọkàn Mọ́kùú wá balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ 100
Kò pé wọn ò tìdí bí ọmọ Jọjọ
tó fẹ́ẹ́ pa
Páwọn Èèbó ló fọmọ ṣe gbígbé nínú-un
yeye
Nígbà ó fẹ́ dọ̀ràn nílé ìwòsàn
Ṣugbọ́n k’a mẹ́nu kúrò lára Mọ́kùú
ká lọ wòyàwó ẹ̀ nílé
Ohun to ń ṣaya ńle kọjáa ti jáwéjura 105
Ń ṣe ló ń dáárìn látojú orun bì ọ̀rọ̀
Àṣééyàn ò nii gbàlùbọ́sà ko hẹ̀fọ́
láyé
A ò ní í gbéwọ̀ sómi kó p’ekú fún wa
Ó ṣèèwọ̀
Ohun a gbìn ní ó hù, ẹni gbin oró kó
rántí ọ̀la 110
Ìkà ò ní í f’oníkà sílẹ̀, ire á maa
bẹ́ni ire.
Báyìí ló ṣèyàwó tó gbákúlá
láìròtẹ́lẹ̀
Tó rọ̀run alákeji, ọ̀run àrèmabọ̀
Ká tún lọ rèé wọmọ Jọjọ níbi ó gbé
ń ṣe tiẹ̀.
Wọ́n láìdúró nijó, ń ṣe lọmọ múṣẹ́
ṣe 115
Ó ti ṣe ohun gbogbo ní gírí mọ́káí, ó
ti kógun jọ.
Wọ́n ti ṣígun tìpá tìkúùkù pàdé Mọ́kùú.
Ọ̀rọ̀ dọ̀rọ̀ tán, ó wa dojú ọlọ́mọ
ò tó o
Àwọn ológun ọmọ Jọjọ ti já ẹ̀ka
igi kọ̀ọ̀kan dání
Láti fi ṣèdáàbòbò iye wọn. 120
Mọ́kùú r’ígi tó ń bọ̀, lóòótó,ọ̀rọ̀
gbàrònú
Ṣùgbọ́n èrò ti tán, èrò tun si kù
“À f’ẹni t’óbìnrin ò tìdí bí, eléyùn-ún-ùn
nìkan
N ló lè rọ́ba mú, lo lè rọ́ba fi ṣeun
K’á sì tó rírú èyí, ó di sánmọ̀ lókè. 125
Báyìí lọbá rò láìmọ̀ pétàdógún ti kù
si dẹ̀dẹ̀,
Pọ́jọ́ ẹ́lẹ́sìn-ín ọbá kọ̀la.
Wọ́n d’ójú agbo, ọ̀rọ̀ dọ̀rọ̀ ìjà
Kìnìún pàdé ẹkùn, nǹkan ṣe
Ojú ìjà kúkú lọmọ Jọjọ ti fi tóba
létí 130
Póbìnrin ò bí òun, ṣe ni a gbe òun nínú
abo.
Èèmọ̀ lu kutu pẹ́bẹ́, ń ṣe lọ́wọ
ọba rọ
Ọmọ Jọjọ toju ọba yọdà, o tẹ̀yin
rẹ̀ kì í s’ákọ̀,
Mọ́kùú ṣe bẹ́ẹ̀, o kú, igí dá!
Mọ́lọmọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ó lọ, nǹkan ṣe. 135
Èyìn èyí náà nìlú fẹnu kò
Pọ́mọ Jọjọ lọbá yẹ
Wọ́n f’ọmọ Jọjọ jọba, ìlú
rọ̀sọ̀mù
Gbogbo wa la kúkú mọ̀ pé 1
Eku tó da’ èyí silẹ̀ là ń pè lẹ́dá. 140
Aya ladárúgúdù
Òun ló sún Mọ́kùú dọ́gbùn-un àìnísàlẹ̀.
N náà ni a wáá kúkú rò pọ̀ o jèe,
N la ṣe ní tá a, bá fẹ́ẹ́ f’áya
Ká ṣàdúà, ká ṣètùtù 145
Ká bọrúnmọlè, ká bòòṣà
Kórí má faya aláya ṣaya fún wa, ẹ
ṣàmín ẹ̀.
No comments:
Post a Comment