Thursday, 4 June 2015

ÌSÌNKÚ ABÍNIBÍ YORÙBÁ




Bóníkẹ́kẹ́ bá fi kú
Tọ́lọ́bọ̀rọ́ bá fò ṣánlẹ̀
Tálábàjà sì ráyé sá
Ǹjẹ́ mo bi ọ ìwọ ọmọ Yoòbá
Báwo lo ó ṣe sin wọ́n?            5
Báwo ni o ó ṣe ṣe ọ̀mẹ̀tọ́
Kí ó se ọ̀mètọ́ tán
Kó o tún ṣọ̀mẹ̀yẹ pẹ̀lú ẹ̀
O tún léyìí kà ọ́ láyà
Ó kà ọ́ láyà ó tóbí fún ọ                   10
O ò fara balẹ̀ o má fòró ẹ̀mí ẹ
O jẹ́ n ṣí ọ lójú n là ọ́ lọ́yẹ
N là ọ́ lọ́yẹ n fọ̀nà hàn ọ́.
Ǹjẹ́ ìwọ tilẹ̀ mọ̀
Pé Yoòbá ò lọ́wọ́ nínú à ń boyún-ún jẹ́?                                           15
Ìyẹn látìbẹ̀rẹ̀ ayé wá
Mo mọ̀ pé o ó bi mí pé
Ó ṣe yé mi
Ojú ò ṣàìmọ̀ ohun tó kúngbá
Ojú ò ṣàìmọ ohun àwó gbà      20
Bòkùú jókùú inú
Bóyá oyún bàjẹ́ ni tàbí ó rọ̀ wàlẹ̀
Inú aṣọ funfun ni Yoòbá
Yóò lọ kò ipọ́n tó ṣe àti ọ̀lẹ̀ tó rọ̀
Lọ sin láàtàn                                   25
Èyí fi hàn gbangba
Pé inú la ti ń ka oyún mọ́ ara wa
Ẹni sì pa irú èyí pààyàn
Ṣùgbọ́n tọ́mọ bá kú ní pínísín
Ní bí ọdún méjì, mẹ́ta, bó tilẹ̀ ṣe
mẹ́fà                                         30
Inú àkísà ni wọ́n ọ́n kó eléyún-ùn sí
Tí wọ́n ó lọ rèé sin sígbóńgbó
Tí wọ́n ó lọ rèé sin sáàtàn
Ṣùgbọ́n tókùú bá ti ń dòkú ọ̀dọ́
Ó ti ń dòkú àgbá nù-un            35
Òkú agbà òkú tó ń gba pósi
Bí wọ́n kò sìn in si ẹsẹ̀ ilé
Wọn  a si ín sí ojútò
Aráyé a sunkun sunkún
Ṣé o ń fọkàn bá ọ̀rọ̀ mi lọ ìwọ ọ̀rẹ́ẹ̀
mi                                            40
Mo rò pé o kò ni ibi í lọ
Torí ọ̀rọ̀ pọ̀ lẹ́nu
Ọ̀rọ̀ pọ̀ létè mo níun-un wí
Mo níun-un wí mo níun-un sọ
Òkú àgbà lòkúu yààrá   45
Òun lòkú ọ̀ọ̀dẹ̀ níbì bàbá ń gbàlejò
Tágbà bá nílé tó lọ́nà, ìlé ni wọ́n ń sin irúu wọn
Táráyé yóò máa jori, jẹ̀kọ, jàmọ̀là, jọ̀kà!
Ọ̀gọ̀rọ̀ọ mèháyà àgbà nìkan ni
Wọ́n ń sìnkú wọn síta gbangba        50
Ìdí ìsìnkú àgbà sílé kọ́ lo sọ?
Ọrọ̀ tún dọ̀rọ̀ à ń relé aláwo dífá
Awó ní á fobì bọríi bàbá ẹni
Èyí kò ní pé a ń fẹ̀dí ẹni sítàa
Inú yààrá ẹni lá ń bọ́ sí ṣerú ẹ̀.           55
Bó sì jẹ́ àdúà la gbà
Tọ́rọ̀ dì bàbá ẹ̀ á gbè é
Inú ọ̀ọ̀dẹ̀ là á tì í ṣawo irúu wọn
Ká kúrò léyún-ùn ká bọ́ síkú awo
Mo ti ń wòkú ògbóni ọ̀ná ti na          60
Ọjọ́ ṣẹ̀ẹ̀ jìnà
Húrùhúrù réè bojú mi mé rí ǹǹkàn kàn
Mo ní kí n kúkú jẹ́wọ́ ọ̀bùn
Kẹ́ẹ́ dáṣọ ró mi
Báwo bá kú awo ní sìnkú awo          65
Ọ̀gbẹ̀rì a sìnkú ọ̀gbẹ̀rì
Tògbóni lojú ò tó, ó tò toníṣàngó bọ̀
Mo mọ bá a ṣeé sìnkú ẹni àrá pa
Bírúu wọn bá kú, oníṣàngó ní í sìnkú wọn
Ètùtù a pọ̀ pọ̀ pọ̀ 70
Gbogbo ohun wọ́n ń mú bọ Ṣàngó  
Ní wọ́n a gbà lọ́wọ́ olúwa rẹ
Ṣójú bọ̀rọ̀ kọ́ lẹlẹ́sìn tọ́húnwá fi ń yin Ṣàngó tẹ́lẹ̀
Torí bóníṣàngó wí lógún
Tó wí lọ́gbọ̀n pẹ̀lú ẹ̀       75
Ẹ̀lẹ́sìn tọ́hùnwá á ní àfi dandan àfi ẹni toun ń sìn      
Ṣùgbọ́n jé kí àrá bù yẹ̀rì
Kó sáná láìrọ̀ òjò
Ẹni a wí á ló dọwọ́ rẹ o Ṣàngó ọkọ Ọya
Àwọn onísànpọ̀nná náà ló ń sin       80
Irú òkúu ti wọn.
Ìyẹn ẹni ìgbóná pa tàbí tí Sànpọ̀nná dàlù
Olóde fúnra rẹ̀, ò sọ gbogbo ilé dahoro
Gbogbo ohun òkú pátápátá ni wọn ó gbà tèfètèfè
Èyí ló jẹ́ kí n mọ pé Yoòbà      85
Mọ Sáyẹ́ǹsì tó pọ̀ jù!                         
Wọn a gbé òkúu sànpọnná pamọ́
Pamọ́ sínú ìkòkò
Omi ara òkú a máa ṣe sọ̀ọ̀rọ̀sọ̀ kalẹ̀
Wọn a nà án sá sóòrùn  90
Bó pẹ́ omi ara a gbẹ,                       
Ibi a bá fẹ́ ẹ sí
Nǹkan a ṣènìyàn
Ọ̀rọ̀ wáá dilé ògún onire ọkòọ̀ mi
Iyèkan agbólú-irin, àjàǹgbódó èrìgì   95
Koriko òdò tí í rú mìnìmìnì            
Bọ́rọ̀ bá dọ̀rọ̀ ẹní fọ̀bẹ gbánú
Tàbí tí ó yànbọn jẹ
Tàbí tá a fọ̀bẹ gbá nínú tàbí tí a yànbọ̀n kò
Àwọn ológùn-ún náà ní í sin wọ́n     100
Láti gbà ìwáṣẹ́                      
Wọn a gbohùn ìnì òkú
Wọn a mu ṣètùtù
Kọ́rọ̀ wáá dorí òkú omi
Ìyẹn ẹni omi gbé lọ tódò rù rè  105
Bóníyemọja bá ń bẹ                      
Àwọn ní í sìnkú wọn sípadò
Wọn a gbà gbogbo ohun ìní ẹní lọ
Wọn a mú ṣètùtù
Mo ti rè, mo ti ṣẹ̀hìndé, èmi ẹni ìgbà kàn    110
Mo rántí ẹni igi wólù, ẹni igí pa   
Ìsìnkú èyí pé méjì n tètè fọ̀
Bó bá kú sídìí igi
Ìdí igi náà nigi í wọ́wé sí
Ṣùgbọ́n tó bá délé ó tóó kú      115
Eléyún-ùn tún  yàtọ̀                       
Ilé ni wọ́n ń sinrúu wọn sí láìsọsẹ̀
Ọjọ́ kò tọ́jọ́ ọjọ́ kò tọ̀jọ̀
Níjọ́ọ bàbá ìsàlẹ̀ ọjà pokùnso
Akíntúndé oníbàtá kò dúró dọlọ́mọle         120
Gbogbo aráyé ń ké, èró ń pariwo  
Ìgbẹ́ ń mì rìyẹ̀
Bí kò sí tàwọn olórò
Òró lòkú ìbá rà sí
Àwọn olórò ló dé wá sìnkú bàbá      125
Àná ni mo tibì kan dé ẹnú kọròyìn 
Níbi mo gbọ́kú adẹ́tẹ̀ lóko wọn
Abọ́dúndé ṣe nǹkan lọ́jọ́ ọ̀hún, ẹ̀rín pànìyàn
Gbogbo ohun ìní adẹ́tẹ̀ ló ko jo lọ́kọ̀ọ̣̀kàn
Ó fi iná sáhéré nígbó tòkútòkú tohun ìní rẹ̀          130
Inú igbó ladẹ́tẹ̀ kúkú ń gbé, ìyẹn ti hàn                                          
Ìbànújẹ́ gbàlú, ọ̀fọ̀ gbòde kan
Níjọ́ táboyún kan fò sánlẹ̀ tó kú
Àwọn olórò layé ké sí wáá sìnkú èèmọ̀
Ọ̀tọ̀ ni wọ́n sìnkú inú, ọ̀tọ̀ ni ti yeye  135
Abuké ti kú, mo gbọ́, eni òrìṣà      
Tẹrùtẹrù labukéé wọ̀lú lèyí mo kọ́ gbọ́
Wọ́n gbẹrù sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹlẹ́rù
Wọ́n ti gbogbo wọn bọ̀ kòkò ọ̀tọ̀
Ìkòkò yìí ni wọ́n yóò gbé lọ igbó      140
Lọọ rì dohun ilẹ̀                     
Ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ̀ wá ń parí bọ̀, ó ku ẹrú ẹni
Ẹrú yàtọ̀ séèyàn gidi, mo ṣe bẹ́ ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀
Abẹ́ ìgbàsọ̀rọ̀ là á sìnkú èyí sí
Kó fìyàtọ̀ hàn       145
Ọ̀rọ̀ dorí onígbèsè tó ń gbówó ẹni kọ́gi  
Orí igi ni wọ́n ń sinrú èyí sí         
Nígbà ìgbà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀
Kó lè fi han aráyé pé gbèsè kò sunwọn
Kúsílé kúsílé sàn jù ká kú sílé àna    150
Aláìnítìjú lọọlé àna rèé kú sí kò wùnìyàn            
Ojúu fèrèsè ni wọ́n ọ́n gbé          
Irú òkú bẹ́ẹ̀ bá jáde
Gbogbo tapá titan á ti já tán kó tóó  yọ
Ọ̀rọ̀ kan eégún ńlá tí í kẹ́yìn ìgbàlẹ̀    160
Èyí n ni ọba                                                         
Báyìí là á ṣe nílée wa, ó ṣèèwọ̀ lọ́hùn-ún nì                                            
Ọ̀nà tí Yoòbáá gbà sin ọba pẹ́gbàágbèje
Sùgbọ́n ohun a mọ̀ ni pé 
Òkú ọlá òkú iyì    165
Lòkú ọba i ṣe
Kárìn ká pọ̀, yíyẹ ní í yẹni
Kò jẹ́ dánìkàn rìn
Erú á lọ
Aya á lọ      170
Òpọ̀ ounjẹ a sì kún sàréè                
Gbogbo rẹ̀ fún jíjẹ lọ́nà òrun
Àrẹ̀mọ ọba tilẹ̀ ń bọ́ba lọ nílẹ̀ ibì kan
Láti rèé jayé!
N ò ní í sọ jèyí ọ̀rọ̀ pọ̀ níkùn   175
Àmọ́ mo fẹ́ẹ́ mẹ́nu ro                     
Kí n mẹ́nu ró kí n mu gáà ife omi
Kí n tìlẹ̀kùn ètè
Lórí ìsìnkú àbìnibí Yoòbá lóriṣiríṣi
Ẹni wà láyé tó ní tòun bàjẹ́      180
Ẹní kú, emi ni ó ṣe?                     
Kólúwa fikú ire pani, iyẹn wùnìyàn!

No comments:

Post a Comment