Mo mọ̀ pé tẹ ẹ bá rèyìí
Mo mọ̀ póhun tẹ́ ó bèèrè
Ni pé, ta ni ń jẹ́ mi?
Ta lèyí tó ń tẹlẹ̀ ṣùàṣùà
Ẹ dákun
ẹ má bínú 5
Ẹ fiyè dé sàlẹ̀ ikùn
Ọmọdé ni mo jé, n ò ṣọ̀yájú
Ìdánwò ni mo gbà, ẹ yé bá mi gbà á
bẹ́ẹ̀
N ò kúkú mọbẹ̀ẹ́ sè
Ẹ má bínú pé ó láta 10
Àwọn àgbà ló bẹ̀ mí ńṣẹ́
Mo sì ṣe kí n sá
Ṣùgbọn ẹni tí Aláàfin bẹ̀ níṣẹ́ ni
Tódò Ọbà sì kún
Ìrònú di méjì, ká bomi sẹ́nu fẹ́ná 15
Iná ò gbọdọ̀ kú, omi ò gbọdọ̀ dànù
Odò ọbà ṣòroó kán lù
Iṣẹ́ ọba ṣòroó ṣàijẹ́
Ni mo ṣe ṣe bí òjíṣẹ́ náà ṣe ṣe
Mo ní kí á fìyànjú ṣe gbígbà
20
Pé bí ó bá kù díẹ̀ káàtó
Kẹ́ ẹ bá mi tún un ṣe
Bó sì ṣe gbígbà bẹ́ẹ̀ náà ni
Kẹ́ ẹ bá mi gbà á bẹ́ẹ̀
Kẹ́ ẹ bá mi fi mọ́ra 25
Kọ́rọ̀ wá dàbí isó inú ẹ̀kú
Kẹ́ ẹ bá mi ṣe é ní àgìdímọ́làjà,
awo Ifẹ̀
Níbi tí àwọn awo ti ń ṣe ìgbọ̀wọ́
ara wọn
Tí títẹ́ sì jìnà sáwoo wọn tèfètèfè
Tọ́rọ̀ wáá dà bí ọmọ babaláwo 30
Tí babaa rẹ̀ dolóògbé
Lọmọ bá bọ́ síwájú àwọn awo
Ló yílẹ̀ sọ́tùn-ún, ló yílẹ̀ sósì
Ló figbe bọnu, ló ń ké tantan
Ó lóun ò mọdá ọwọ́ 35
Òun ò mọkẹrẹrẹ Ẹbọ íha
“Ẹwáá bá mi tọ́rọ̀ yí ṣe o, ẹ̀yin
àgbà”
Ǹjẹ́ àbọ̀ mi rè é o
N ò mọ̀kan
N ò mọ̀kàn
40
Ẹ dákun ẹ bá mi gbà á bẹ́ẹ̀
Kẹ́ ẹ fìyókù ṣàforíjìì mi
No comments:
Post a Comment