Saturday, 28 April 2018

Atóka Ìǹfínítíìfù (Ọ̀rò-ìṣe òbòró)


Enu àwon onígírámà kò kò lórí ohun tí ó ń tóka òrò ìse òbòró ní èdè Yorùbá. Àpeere òrò-ìse òbòró  ni a fa igi sí nídìí yìí: Ó mo okò ó wà. Isé tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan se lórí òrò ìse òbòró ni a ó yè wò. Awon kan so pé àfòmó ìbèrè /í/ ni ìpìlè rè. Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ta ko àbá yìí nítorí pé fáwèlì olóhùn òkè kì í bèrè òrò ní èdè Yorùbá àti pé tí a bá fi àfòmó sèdá òrò, òrò tuntun ló máa ń ti ibè yo sùgbón àpólá ìse òbòró, gégé bí ó se hàn nínú gbólóhùn yìí (ó mo okòó wà), kìí se òrò tuntun. Àbá kèjì tí ó wáyé lórí òrò ìse òbòró ni pé ara ìsodorúko àpètúnpè elébe (KíKF) tàbí ohun tí àwọn kan pè ní àfàmọ́ kọ́ńsónáǹtì ni ó ti wa. Sùgbón ọ̀jọ̀gbọ́n yìí so pé èyí kò lè rí béè nítorí pé ìró pípaje lásán ko ye kí ó yí ìtumò padà béè rè é ìtumò àwon ìpèdè méjèèjì yìí yàtò sí ara won: Òjó fẹ́ rírọ̀ # Òjó fẹ́ẹ́ rọ̀, Òjà kò ní títà # Òjà kò níí tà. Yàtò sí èyí, ìsodorúko onihun KiKF kò lè jeyo nínú àsínpò-ìse bí òrò-ìsè òbòró se lè jeyo, ba: Adé fé é wá á bèrè í kọ́ iṣé ẹ́ ṣe # *Adé fé wíwá bíbèrè kíkó ise síse.  A lè pe àkíyèsí alátenumó sí ìhun oni-KíKF, a kò lè se èyí sí ihun alápólà ìse òbòró, ba: Adé pé lílo-ilé à lílo ilé ni Adé pé sí, * Adé pé é lo ilé à *é lo ilé ni Adé pé sí. A lè so pé Isé sòro ní síse  fún ìhun oní-KíKF, a kò lè so pé *Iṣẹ́ sòro ní í ṣe fún àpólà ìse òbòró. Àpólà tí a fa igi sí nídìí ninú àpólà ìse òbòró, Mo fé é máa lo sì jé àpólà ìse sùgbọ́n ti ìhun oní-KíKF yìí, *Mo fé mímáalọ kìí se àpólà ìse. Gbólóhùn oní ìhun KíKF yìí ní ìtumò méjì: Ó mo okò wíwà (i: ó mo bí a se ń wa okò, ii: ó mo okò tí a lè wà) sùgbón ìtumò kan ni gbólóhùn olórò-ìse òbòró máa ń ní: Ó mo okò ó wà = Ó mo bi a se ń wa okò. Tí ó bá jé pé ìhun oní-KíKF ni ìpìlè òrò-ìse òbòró ni, gbogbo àìbáramu tí a se àkíyèsí lókè yìí kò ye kí ó wáyé. Àwon kan tún so pé láti ni ìpìlè atóka òrò-ìse òbòró. Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ní èyí kò lè rí béè nítorí pé kò sí bí a se lè pa ìró je títí tí atóka òrò-ìse òbóró fi lè je yo láti inú ‘láti’ nínú gbólóhùn kejì yìí: Mo fé láti lo àti Mo fé é lo. Ní ìparí, Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí wá so pé kò nílò pé a ń topa òrò-ìse òbòró lo sí ibì kankan nítorí pé nínú àwon èdè tí ó sún mó Yorùbá, irú nǹkan kan náa ni wón fi ń tóka òrò-ìse òbòró won kì í sì í topa rè lo sí ibì kankan, fún àpeere:                                                 
                                                                                   Yorùbá             Mo fé é rí i
                                                                                    Ìgbò:                Achor-m
                                                                                    Yorùbá            Ó bèrè sí í sokún
                                                                                    Ìgala                I tsare e raku
Àwon atóka òrò-ìse òbòró ni a fa igi sí n ídìí nínú  àwon òrò yìí. Níwon ìgbà tí àwon èdè wònyí kò ti topa atoka òro-ìse òbòró won lo sí ibì kankan, Yorùbá náa kò nílò láti topa tirè náà lo sí ibi kankan.

No comments:

Post a Comment