Monday, 30 April 2018

ÀPÓTÍ ALÁKÀRÀ


ÌSỌNÍṢÓKÍ ÌWÉ ÀPÓTÍ ALÁKÀRÀ
            Ìwé Àpótí Alákàrà jẹ́ ìwé tí DÉBỌ̀ AWẸ́ kọ ní ọdún 2010; ilé-iṣẹ́ tí ó tẹ ìwé yìí jáde ni ELYON PUBLISHERS[1].
            Débọ̀ Awẹ́ jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ nínú ìwé kíkọ lédè Yorùbá. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú èdè Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ilé-Ifẹ̀ àti Yunifásítì tó wà nílùú Ìbàdàn. Ìran ni òǹkàwé fi hun ìtàn yìí pọ̀ tí àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìran méjìlá.
Ìran Kìn-ín-ní
            Ní ìran kìn-ín-ní, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbí ni pé Kàrímù ń bá ìyàwó rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní àárọ̀ kùtùkùtù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jí. Àbẹ̀ó tí ó jẹ́ ìyàwó Kàrímù kúnlẹ̀ tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí ki ọkọ rẹ̀ ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá bákan náà ni Kàrímù náà ń ki ìyàwó rẹ̀ tí àwọn méjèejì sì gbé òṣùbà fún ara wọn; kò pẹ́ ni ó bojú wẹ̀yìn tí ó sì rí Àńwòó tíí ṣe ọmọ wọn tí Kàrímù sì ń bi í léèrè pé ibo ni ó sùn ṣùgbọ́n tí Àbẹ̀ó tíí ṣe ìyá Àńwòó ń gbawájú tí ó ń gbẹ̀yìn pé inú ilé ni ó sùn tí Kàrímù sì ń sọ pé ọmọ ha lè sun inú ilé kí ó ró dẹ́dẹ́ kó kàn dudu láàrọ̀ kùtù báyìí?
            Àbẹ̀ó sọ pé òun ni òun ṣílẹ̀kùn fún Àńwòó nígbà tí ó wọlé, tí èyí sì bí Kàrímù nínú tí ó fẹ́ na Àńwòó ṣùgbọ́n tí Àbẹ̀ó kò fún un láyè láti nà án; kódà ṣe ni Àbẹ̀ó tún ń sọ fún ọkọ rẹ̀ pé bí ọmọ bá ti jáde ìwé mẹ́wàá, ó ti yẹ kó gba òmìnira lọ́wọ́ òbí; gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí Àbẹ̀ó ń sọ nìyí tí ó fún Àńwòó ní ìgboyà láti máa rin ìrìnkunrìn. Kàrímù wá dojú kọ àwọn èrò ìwòran tí ó sì ń sọ fún wọn pé òun ń fẹ́ kí àwọn pawọ́pọ̀ láti bá ọmọ wí kí àwọn lè tọ́ ọ sí ọ̀nà tí ó yẹ ṣùgbọ́n tí ìyá rẹ̀ kò jẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀, bí òun bá ti ń gbé e sókè bẹ́ẹ̀ ni Àbẹ̀ó, ìyàwó òun, yóò máa rẹ̀ nílẹ̀. Àńwòó náà tún ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà pé bí ọmọ bá ti kúrò lọ́wọ́ nínà, àwòmọ́jú ló kù àti wí pé kí ẹnìkan máà dún mọ̀huru, mọ̀huru mọ́ òun o. Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn méjèèjì láàárọ̀ ọjọ́ yìí nìyìí. Lẹ́yìn èyí ni Kàrímù ká ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ mọ́ ọn lẹ́nu tí Àńwòó sì ta gìrì; bẹ́ẹ̀ ni Kàrímù sọ fún un pé bí ó bá ti ṣe tán kí ó lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ òun Sàámú tó lóun ó bá a wáṣẹ́ tíṣà. Bóyá bó o bá níṣẹ́ lápá, ìrìn àrè rẹ̀ bíi takọ ajá á tún dín kù díẹ̀.
Ìran Kejì
            Ní ìran yìí ni Kàrímù ti sọ fún Àńwòó láti lọ sí ọ̀dọ̀ Sàámú tíí ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó fẹ́ bá a wá iṣẹ́ tíṣà tí Sàámú sì sọ fún Àńwòó wí pé orí rẹ̀ náà ni òun wà àti wí pé yóò bọ́ sí i. Bí Àńwòó ṣe fẹ́ máa lọ ni Sàámú rí ìkọ̀yìnsí rẹ̀ tí ó sì pè é padà láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí ìmúra rẹ̀, ṣùgbọ́n bí Sàámú ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ ni ó ń rúnmú tí ó sì kọ ìhà kòkànmí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún un.
Ìran Kẹta
            Ní abẹ́ ìran yìí ni a ti rí Kàrímù tí ó jókòó tí ó sì ń hun agbọ̀n kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Àdìó tó bá a níbẹ̀ tí wọ́n sì jọ fi ọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ lórí bí ìlú àti bí iṣẹ́ ṣe rí tí Àdìó sì bèèrè Àńwòó tí ó jẹ́ ọmọ Kàrímù. Nígbà tí Àńwòó bá wọn ní ibi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí ó kí wọn gán-ún tí èyí sì bí Àdìó nínú tí ó fi ń bá Kàrímù sọ̀rọ̀ nípa ìmúra tí ó mú tí ó sọ wí pé èyí kò bá ojú mu. Kàrímù sọ fún Àdìó wí pé nítorí ohun tí ó ń ṣe ìyá rẹ̀ kò jẹ́ kí ǹ bá a wí, ìdí nìyí tí mo fi sọ fún ọ̀rẹ́ mi Sàámú láti bá a wá iṣẹ́ tíṣà ṣùgbọ́n tí Àdìó sọ wí pé iṣẹ́ àgbẹ̀ wà tí ìjọba fẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ ṣùgbọ́n tí Kàrímù sọ wí pé òun kò rò wí pé Àńwòó yóò lè ṣe é nítorí pé ológe wíwúwo ni. Ohun tí Kàrímù tẹnu mọ́ ni wí pé kí Àńwòó tiẹ̀ rí iṣẹ́ kan ṣe kí ó lè dẹ́kun ìwà ìrégbè tí ó ń hù.
Ìran Kẹrin
            Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, Oyè tíí ṣe ọ̀rẹ́kùnirn Àńwòó ń ta ayò lúdò ní pálọ̀; ẹnu ayò yìí ni Bánjọ bá wọn; kí a má fa ọ̀rọ̀ gùn, ohun tí Bánjọ wá bá Oyè fún ni láti bá a sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí àwọn jọ ń wá wí pé òun ti lọ fi orúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ìjọba pèsè fún wọn, ṣùgbọ́n nígbà tí Bánjọ dé ibẹ̀ nǹkan mìíràn ni ó bá lẹ́nu Oyè. Ohun tí ó wí ni pé ohun kò tá sí owó kéékèèké tí yóò máa wá láti ibi iṣẹ́ àgbẹ̀ àmọ́ táósàn ni òun ta sí níbi bísínẹ́ẹ̀sì. Ohun tí òun yoò ṣe nìyẹn; kò pẹ́ tí Bánjọ fi kúrò ní ibẹ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì kò papọ̀ mọ́.
Ìran Karùn-ún
            A rí Àbẹ̀ó tí ó jẹ́ ìyàwó Kàrímù tí ó sì jẹ́ ìyá Àńwòó bákan náà tí o ń kọrin òwe tí ó fi ń bú ọkọ rẹ̀ nígbà tí ó gbọ́ pé ọkọ òun ti dé tòsí. Èyí mú kí inú bí Kàrímù díẹ̀ tí ìyàwó rẹ̀ fi ń bi í léèrè pé ṣé ó bá wọn? Tí ó sì fún un lésì pé ibo ni ó rán òun. Kàrímù tún fi ọkàn tútù bá a sọ̀rọ̀ wí pé ohun tí òun fẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ ni pé kí àwọn wá ibìkan ki ìdí ọmọ yìí bọ̀ kí ó lè jáwọ́ nínú ìranù ṣíṣe ṣùgbọ́n nígbà tí Àbẹ̀ó yóò sọ̀rọ̀, ó ní ọmọ tòun kò lè ṣiṣẹ́ ìdọ̀tí kí ọmọ́ jáde ìwé mẹ́wàá kí ó máa fi ṣiṣẹ́ àgbẹ̀; òun kò fẹ́ bí kò ṣe iṣẹ́ akọ̀wé ni òun fẹ́ fún ọmọ òun àti wí pé bí ó bá jẹ́ pé ẹyọ ẹnìkan ni wọ́n fẹ́ẹ́ gbà ṣíṣẹ́, ọmọ òun ni yóò jẹ́. Kàrímù tún sọ fún un pé òun fẹ́ kí àwọn jọ pawọ́ pọ̀ bá ọmọ yìí wí ni àti wí pé tí ó bá ní iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ́wọ́ tí iṣẹ́ tíṣà sì tún bọ́ sí i, ó fi ń dáa ni ṣùgbọ́n ohun tí Àbẹ̀ó takú ni pé iṣẹ́ àgbẹ̀ ọmọ tòun kò lè ṣeé tí èyí sì tún fa kí Kàrímù tún bínú tí ó sì korò ojú sí ohun tí Àbẹ̀ó ń sọ. Bẹ́ẹ̀ ni Àbẹ̀ó náà wá gbaná jẹ tí ó sì ń tahùn sí ọkọ rẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀.
Ìran Kẹfà
            Ní ibi ayẹyẹ kan, a rí Ìbítóyè bí olúyoko tí ó ń darí ètò. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ètò, wọ́n pe alága, bákan náà ni wọ́n pe amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ alága tíí ṣe Àńwòó. Oríṣìíríṣìí ènìyàn tí ó wà lágbo tí ó rí Àńwòó ni ó ń sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe múra tí ò dùn-ún rí mọ́ ènìyàn. Níbi ayẹyẹ yìí bákan náà ni a ti rí oníròyìn kàyéfì tí ó ka àwọn ìròyìn tí ó jẹ́ kàyéfì tí ó sì pa àwọn ènìyàn lẹ́rìn-ín, nígbà tí wọ́n ka ìròyìn tán ni wọ́n pe àwọn tó ń ṣe ayẹyẹ láti wá fẹsẹ̀ rajó tí wọ́n sì pe àwọn tí ó ṣe alága náà pẹ̀lú wọn, níbẹ̀ ni àwọn tó mọ Àńwòó ti ń sọ̀rọ̀ pé ìyàwó Oyè ni ó ń bá ẹlòmíràn jó yìí tí wọ́n sì fẹnu kò sí pé bí obìnrin ṣe máa ń ṣe nìyẹn; ẹnu ijó yìí ni àwọn méjèejì wà tí ijó sì ti wọra tí Oyè fi wọlé sí ojú agbo tí ó sì rí Àńwòó pẹ̀lú ẹlòmíràn tó ń jó tó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí wọ̀dìmú pẹ̀lú Òjògbèdè tí patí fi dàrú tí wọ́n sì daṣọ bo ìtàgé.
Ìran Keje
            A rí Oyè tí ó wá sí ilé awọn Àńwòó, tí ó sì bá Kàrímù tíí ṣe bàbá Àńwòó ní ìta; Kàrímù ń bi Oyè léèrè oríṣìí ọ̀rọ̀ láti lè mọ irú ẹni tí ó jẹ́ sí ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí Àbẹ̀ó ti ń gbawájú tí ó ń gbẹ̀yìn tí ó sì ń sọ fún Kàrímù pé èwo ni àbùrọ̀ máa lọ àlejò ọmọ nífun báyìí àti wí pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni tí wọ́n jọ jáde ìwé mẹ́wàá láìpẹ́ yìí; kò pẹ́ púpọ̀ ni Àńwòó náà jáde tí ó sì sọ fún Oyè pé ki ó máà dá bàbá òun lóhùn. Lẹ́yìn èyí ni Àńwòó bẹ Oyè pé kí ó máà bínú ọjọ́ tí Oyè sì sọ fún un pé nígbà tí ó ti wá tí ó sì ti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí ni òun ti gbàgbé ẹ̀. Oyè sọ fún Àńwòó wí pé iṣẹ́ kan ló yọjú tí òun wá fi tó o létí wí pé ọ̀rẹ́ òun kan tó wà ní India ni ó fi egbò igi olóró ránṣẹ́ láti bá a gbé e lọ sí ìlú Amẹ́ríkà tí Àńwòó sì korò ojú sí i wí pé tí òun bá ń wáṣẹ́ kìí ṣe bí irú èyí àti wí pé ẹ̀mí òun kò gbé e. Ṣùgbọ́n nígbà tí Oyè sọ iye owó tí ó wà nínú iṣẹ́ yìí fún Àńwòó, ó fara mọ́ ọn tí wọ́n sì fìpàdé sí ọjọ́ kejì tí Àńwòó sì sọ fún Oyè wí pé òun kò níí sọ fún bàbá òun; kódà irọ́ kan ni òun yóò pa fún ìyá òun.
Ìran Kẹjọ
            Ní ìdí ìrókò àwọn aṣọ́bodè ń yẹ àwọn ẹrù wò tí wọ́n sì ń wò ó fínnífínní, wọ́n eyẹ ẹrù obìnrin kan wò ṣùgbọ́n tí ó ní ẹrù tí kò bá òfin mu nínú tí wọ́n sì gba owó pẹ̀lú ẹrù tí ó níyelórí lọ́wọ́ rẹ̀; bí wọ́n ti fẹ́ẹ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn Oyè àti Àńwòó ni Oye ti bẹ̀rẹ̀ sí níí p’ọfọ̀ àti ògèdè tí ó sì sọ fún Àńwòó kí ó tẹ̀lé òun, kò sì gbọdọ̀ wẹ̀yìn, ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn aṣọ́bodè yìí ti rí wọn tí ó sì ń pariwo pé kí Àńwòó dúró ṣùgbọ́n tí Oyè sọ fún un pé kò gbọdọ̀ dúró; lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti rí i wí pé awọn aṣọ́bodè yìí ti ń lé àwọn ni wọ́n bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ tí àwọn asọ́bodè sì yìnbọn si Oyè tí ó sì kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Àńwòó kò dúró ni aṣọ́bodè bá ju kóńdó ọwọ́ rẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀ tí ó sì ṣubú; nígbà tí aṣọ́bodè yìí dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú fún eré tí ó gbé aṣọ́bodè náà sá. Nígbà tí wọ́n tú àpò Oyè, tí wọ́n rí òògùn olóró pẹ̀lú owó tùùlù.
Ìran Kẹsàn-án
            Àbẹ̀ó lọ sí ọ̀dọ̀ Babaláwo láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ti jáde nílé láti bí oṣù méjì tí kò sì wálé tí Kàrímù tíí ṣe baba rẹ̀ sì ti ń bèèrè ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ babaláwo tí ó sì bá Ifá ní gbólóhùn, ohun tí ó sọ fún un ni pé kí ó rúbọ nítorí ẹni tí ó wá béèrè ọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ kí ó má baà já sí ikú bẹ́ẹ̀ ni babaláwo sì ka àwọn èròjà ẹbọ fún un tí ó sì dágbére ọjọ́ kejì fún babaláwo láti kó ohun ẹbọ wá.
Ìran Kẹwàá
            Àbẹ̀ó lọ sí ọ̀dọ̀ Àlàkẹ́ tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti lọ yá owó tí ó fẹ́ fi ra nǹkan ètùtù tí babaláwo sọ fún un láti rà ṣùgbọ́n tí Àlàkẹ́ sọ fún un pé kò sí owó kankan lọ́wọ òun àti wí pé owó ilé-ẹ̀kọ́ Ṣẹ̀rí, ọmọ òun, ni òun ń wá báyìí, tí ó sì gbà á ní ìyànjú láti lọ ba baálé rẹ̀ ṣùgbọ́n tí Àbẹ̀ó sọ pé Kàrímù kò níí gbọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò níí gbà ni Àbẹ̀ó bá dá ọgbọ́n kan, tí ó sì sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé kí ó tẹ̀lé òun dé ilé láti sọ fún ọkọ òun pé ní ilé yẹ̀míwò tí òun lọ ni wọ́n ti sọ pé kí ọkọ ọ̀rẹ́ òun rúbọ torí ikú òjijì, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Kàrímù, gbogbo nǹkan tí wọ́n sọ kò wọ̀ ọ́ ní etí rárá.
Ìran Kọkànlá
            Kàrímù pe ìpàdé ẹbí lé Àbẹ̀ó lórí láti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínù ẹbí wọn àti wí pé kí ó lè sọ ibi tí ó mú ọmọ òun lọ, bóyá ó ti fi lọ́kọ ni àbí ó ti rán an lọ sí ibòmíràn; nígbà tí gbogbo àwọn àgbààgbà sì sọ̀rọ̀ tán tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Àbẹ̀ó náà, kò pẹ́ ni ẹnìkan pọn Àńwòó dé tí ẹsẹ̀ ti kán tí wọ́n sì lẹ nǹkan mọ́ ọn ní gbogbo orí. Gbogbo ẹbí sọ̀rọ̀ sí Àbẹ̀ó lórí bí ó ṣe tọ́ ọmọ rẹ̀ tí wọ́n sì sọ pé kí ó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Ìran Kejìlá
            Bánjọ ti di olówó ní ìdí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ó sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ iṣẹ́ àti wí pé iṣẹ́ tí ó yàn láàyò ti fẹjú sí i, inú ìyẹ̀wù ni Bánjọ wà tí Àńwòó ti ń bèèrè rẹ̀ tí ó sì bá àwọn ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń bi Àńwòó léèrè oríṣìíriṣìí ìbéèrè láti lè mọ̀ bóyá ọ̀gá ni ó ń wá, nígbà tí Àńwòó sì rí Bánjọ, ẹnu yà á tí ó sì rántí bí àwọn ṣe máa ń fẹnu ṣáátá rẹ̀; lẹ́yìnòrẹyìn, owó ni Àńwòó wá tọrọ lọ́wọ́ Bánjọ nígbà tí bàbá ti kọ̀ ọ́ ṣùgbọ́n tí Bánjọ sọ fún un pe tí òun bá fún un lówó, owó á tán ṣùgbọ́n tí ó bá lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ òun, kò burú tí Àńwòó sì gbà sí i lẹ́nu tí ó sì pàṣẹ láti mú Àńwòó lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà kí wọ́n lè tọ́jú rẹ̀ dáadáa.
            Ẹni tí ó jẹ́ olú ẹ̀dá-ìtàn nínú ìwé yìí ni Àńwòó tí àwọn yòókù sì jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́.

ỌNÀ ÈDÈ
Òwe
·                     Eeṣin tó bá bólóde rìn, yóò mu ẹ̀jẹ̀ lọ́pọ̀
·                     Alagẹmọ tó ǹ yọ jayé, ikú ń pa á, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tọ̀pọ̀lọ́ tó ń gbé ara rẹ̀ ṣánlẹ̀
·                     Adáǹpárá fòfòòfò, ó forí sọgi, ó lọ́pẹ́lọpẹ́ ojú òun, ì bá lójú lágbárí ì bá forí gbági?
·                     À ń wẹ́ni tó lẹ́yìn gbọ́mọ fún, abuké bọ̀ óde
·                     Ìlérí aláǹgbá lọ̀rọ̀ rẹ̀, ìhàlẹ̀ ẹbọ
·                     Okó ṣée ro làgbẹ̀dẹ rọkọ́ tà
·                     Èèyàn méjì níí jẹ̀bi okòó, ẹni a yá lókòó tí ò san-án àti ẹni yáni lókòó tí ò lè yááfì rẹ̀.
·                     Èkúté tó fàkọ̀ sílẹ̀ tó ń jẹ ọ̀bẹ lọ̀rọ̀ yín, tẹnu ẹni ló fẹ́ẹ́ gbọ́
·                     Ṣé orí ìjókòó lahunṣọ wà títí tí ọ̀kẹ̀rẹ̀kẹrẹ ó fi wọ́ dọ́dọ̀ rẹ̀
·                     A kìí ni kọ́mọ má hu eyín ganganran, tó bá ti lè rí ètè òkè fi bò ó
·                     Bí páálí ẹ̀ẹ̀kẹ́ ọmọ ẹranko ò bá bàjẹ́ ti ọmọ ènìyàn kìí dùn
·                     A kìì ṣòòṣà lódò kí làbẹlàbẹ ìdí ó má mọ̀
·                     Lójú adẹ́tẹ̀, gbogbo ayé lòmùgọ̀
·                     Pẹ̀lẹ́ là á fií pa èèrà ká tó lè rí ìfun rẹ̀ kó
·                     Bọ́mọdé bá láṣọ bí àgbà, kò le lákìísà bí àgbà
Àfiwé Tààrà
·                     Ó ń yán hóó bí ẹṣin
·                     Òkú àròyé bí ẹyẹ ìbáákà
·                     Ìrun ara rẹ̀ bíi takọ ajá
·                     Ayé tó fúyẹ́ bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀
·                     Ó jó bíi kòkòrò
·                     Òkú ẹnu bí àòko
·                     Yajúlé kiri bí oníbáárà
·                     Ẹ ẹ̀rí i bó ṣe ká bí ẹni tó lúgọ sídìí ìrókò


Ìwé Ìtọ́kasí

Awẹ, Debọ (2010), Àpótí Alákàrà. Ilesa: Elyon Publishers.


[1] Odunyemi Sunday Adebayo ni ó kọ bébà yìí.

No comments:

Post a Comment