Wednesday, 3 June 2015

Yoruba Monosyllabic Words (Yorùbá -Yorùbá)


 Aa


á: (i) atọ́ka àsìkò ọjọ́ iwájú: A á lọ (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo rà á (iii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní ọ̀pọ̀ ní ipò àbọ̀: Ó nà án.

a: (i) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà: A lọ (ii) ènìyàn: A kì í dàgbà má lábẹ̀ (iii) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: bẹ --->abẹ (iv) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo gbà á (v) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní ọ̀pọ̀ ní ipò àbọ̀: Ó rí a.

à: (i) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: bọ̀ ---> àbọ̀ (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà: À á lọ (iv) atọ́ka ìtẹnumọ́: A rà á à.

án: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó tàn án jẹ.

an: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó kán an sí méjì.

àn: atọ́ka ìtẹnumọ́: Ó nà án àn.


Bb


bá: (i) tẹ̀lé: Ó bá mi lọ (ii) ṣe nǹkan fún: Ó bá mi gbá ilẹ̀ (Ó gbá ilẹ̀ fún mi) (iii) ràn lọ́wọ́: Ó bá mi ṣe é (Ó ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe é) (iv) fẹ́: Ẹni tí ó bá ń lọ kí ó máa lọ (Ẹni tí ó bá fẹ́ lọ kí ó máa lọ) (v) subú: Ibí bá wọn (Ibí subú tẹ̀ wọ́n).

ba: fi ara pamọ́: Ọmọ náà ba sí abẹ́ igi.

bà: (i) tóó sá lóòrùn: Kòkó náà ti bà (ii) dúró lórí: Ẹyẹ náà bà lé orí igi (iii) mọ́: Ó ba egbò rẹ̀ (v) kàn ní ara: Òkúta tí ó sọ bà mí (vi) jáyà: Ẹ̀rù bà mí.

bẹ́: (i) fọ́: Ó bẹ́ pẹ̀ẹ́ (ii) gé: Ó bẹ́ ẹ ní orí (iii) fò: Ọmọ náà bẹ́ kọjá lórí igi náà (iv) rà: Ó bẹ́ tábà (v) gbó: Orógbó náà bẹ́ (vi) bẹ̀rẹ̀: Ọ̀ràn ti bẹ́ (vii) tú afẹ́fẹ́ jáde: Táyà mọ́tò náà bẹ́ (viii) tu: Ó bẹ́ itọ́.

bẹ: (i) tàn: Ó bẹ yòò (ii) sí eèpo: Ó bẹ iṣu náà (iii) sọ̀rọ̀ akọ: Ó bẹ sí mi (iv) wà: Ó ń bẹ (v) yájú: Ọmọ yẹn bẹ jù.

bẹ̀: tọrọ àforíjì: Ó bẹ̀ mí fún bíbú tí ó bú mi.

bí: (i) jẹ́ kí ó wáyé: Ó bí ọmọ (ii) lẹ́yìn tí: Bí o nà mí, n ó nà ọ́ (iii) àtọ́ka ìbéèrè: Ó lọ bí? (iv) ọ̀nà ìṣe nǹkan: Ó kọ́ mi bí a ṣe ń ṣe é (v) mọ́fíìmù ìsọ gbólóhùn di orúkọ: Ó ní àfi bí òun pa á (vi) Nígbà tí: Bí ó ti rí mi, inú rẹ̀ dùn (vii) jọ: Ó rí bí Olú.

bi: bèèrè: Ó bi mí ní ọ̀rọ̀.

bì: (i) pọ̀: Ó bi oúnjẹ tí ó jẹ (ii) tì: Ó bì wọ́n sẹ́yìn (iii) yọ oríṣìíríṣìí àwọ̀: Aṣọ náà ń bì.

bó: (i) hó: Ó bó eèpo ọsàn (ii) ṣí: Ó bó awọ ejò (iii) ya: Mo fi ara bó.

bo: fi ara pamọ́: Ó bo sí abẹ́ igi.

bò: (i) dé: Ó bo abọ́ náà (ii) ní ewé púpọ̀: Igi ìrókò náà bò.

bọ́: (i) lọ sílẹ̀: Ọsàn náà bọ́ (ii) fún ní oúnjẹ: Ó bọ́ ọmọ rẹ̀ tí ebi ń pa (iii) fọ̀: Ó fi omi bọ́ ojú (iv) mú kúrò: Ó bọ́ ẹ̀wù ní ọrùn (v) kì mọ́lẹ̀: Ó bọ́ ilẹ̀ (vi) to ewé sí: Ó bọ́ ilé (vii) lọ: Ó bọ́ sí ẹ̀hìnkùnlé (viii) ṣí kúrò: Ejò náà bọ́họ.

bọ: sìn: Ó bọ òrìṣà.

bọ̀: (i) dé: Ó ń bọ̀ (ii) sè dáàyè kan: Ó ń bọ ẹran (iii) fi òwú sí ní inú: Ó ń bọ abẹ́rẹ́ (iv) gbé wọ̀: Adé bọ ẹ̀wù (v) di ọwọ́ mọ́ ọwọ́: Adé bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.

bọn: di ogbó: Aṣọ rẹ̀ ti bọn:

bú: (i) sọ̀rọ̀ àìdáa sí: Ó fi èébú ara mi bú mi (ii) fọ́: ìkòkò náà bù ní ìdí (iii) kígbe: kìnìún bú.

bu: bàjẹ́: Ẹ̀bà náà ti bu.

bù: (i) fi pa: Ó ti fi ọwọ́ bù (ii) mú díẹ̀ lára odidi: Mo bu iṣu jẹ (iii) fẹ́rẹ̀: Mo bù dé ilé tán (iv) sè: Ó bu iṣu nínú iná (v) fi fún: Ó bu ọlá fún un.

bùn: ‘fún’: Ó bùn mi ní owó. 


Dd


dá: (i) mú wáyé: Ọlọ́run dá ènìyàn (ii) ṣe nǹkan fúnra ẹni nìkan: Ó dá jẹun (iii) láìṣàìsàn: Ara mi dá (iv) fi sílẹ̀: Mo dá owó (v) mú ẹnu ró: Òjò dá (vi) jàn mọ́lẹ̀: Ó dá mi nínú ìjàkadì (vii) fi lù: Ó dá mi ní igi (viii) kán: Ó dá igi náà sí méjì (ix) kọ: Ó dá ọpẹ́ (x) fi fún: Ó dá ọpẹ́ (xi) láìní nǹkan: Ọ̀dá owó dá a (xii) ṣófo: Ọjà dá (xiii) yọ lẹ́nu: Sòbìà dá a (xiv) Ìkáàánú: Igí dá (xv) kí ó wálẹ̀: Ojú rẹ̀ ti dá. (xvi) Kí a máà ní àánú: Ojú rẹ̀ ti dá.

dà: (i) jẹ́ kí ó ti ibì kan bọ́ sí ibòmíràn: Ó da omi sí inú abọ́ (ii) jẹ́: Kí ló dà? (iii) níbo ló wà? Ìwé náà dà? (iv) gbé ọmo sí ẹ̀gbẹ́ láti ẹ̀yìn: Ìyá náà da ọmọ rẹ̀ (v) ran: Ó da òwú (vi) sọ ibi tí yóò gbà: Ó ń da ẹran (vii) kí ebi pa ni: Oúnjẹ mi ti dà (viii) jọ rìn pọ̀: Wọ́n ń dà yọyọ lọ (ix) di gbígbà: Ẹbọ dà (x) tàn: Ó dà mí (xi) láìbọ́ sí ọ̀kánkán: Ojú rẹ̀ dà (xii) jẹ́ kí oúnjẹ jáde ní ẹnu: Ọmọ náà dà.

dán: kọ: Tábìlì náà dán. A fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa wo ara wa nínú rẹ̀.

dan: ṣe oògún sí ẹni tí ó kọ́kọ́ dán oògùn wò: Ó dan egúngún náà  ní ojú eré.

dé: (i) bọ̀ láti ibì kan: Mo ti ti oko dé (ii) bò: Ó dé oúnjẹ rẹ̀ kí kòkòrò má baà wọ inú rẹ̀ (iii) wà ní ibi tí a ń lọ: Mo ti dé ilé (iv) bẹ̀rẹ̀: Òjò ti dé, ẹ jẹ́ kí a wọlé kí aṣọ wa má baà tutù (v) ní: Owó ti dé sí i ní ọwọ́ (vi) wọ̀: Ó dé fìlà.

dè: (i) dì: Ó dè é lókùn (ii) retí: Ó jókòó dè mí.

dẹ: (i) wá ẹran fún pípa nínú igbó: Ó ń dẹ ìgbẹ́ (ii) ṣe okùnfà: Mo dẹ wọ́n sí ara kí wọn lè bá ara wọn jà. 

dẹ̀: (i) gọ̀: Ó ti dẹ̀ jù. A lè ní kí ó ti ọwọ́ bọ iná kí ó ti ọwọ́ bọ̀ ọ́ (ii) rọ̀: Ògẹ̀dẹ̀ pípọ́n máa ń dẹ̀ ju dúdú lọ (iii) dínkù: Ikọ́ mi ti dẹ̀.

dí: fi nǹkan bò: Ó dí ihò eku náà,

dì: (i) dà: Ó di gbígbẹ (ii) dè: Ó di igi (iii) wọ̀ sí ìdí: Ó di bèbè (iv) kí ìfẹ́ máà sí fún nǹkan: Ó dì gbọ́nkú sí ọ̀rọ̀ náà (v) ṣe ní ọ̀ṣọ́: Ó di irun rẹ̀ (vi) yí padà sí bí òkúta: Omi náà ti dì (vii) àìbẹ́gbẹ́ ṣe: Ó di ara púpọ̀ jù. Òun nìkan ni ó máa ń rìn.

dín: (i) fi epo gbígbá sè: Ó dín dòdò (ii) ta ọjà ní ọ̀pọ̀: Ó dín mi ní owó ọjà. N kò san tó iye tí ó kọ́kọ́ pè é.

dó: (i) fi ṣe ilé: Ó dó sí Ìbàdàn (ii) ọ̀rọ̀ àlùfàǹsá fún níní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú obìnrin:  Ó dó ìyàwó rẹ̀ (Ó bá ìyàwó rẹ̀ sùn).

dò: nǹkan kan: Kò mọ dò.

dú: (i) pa: Ó dú ẹran náà (ii) sọ di dúdú: Ó rẹ ẹ́ dú.

du: sáré: Ó du lọ.

dù: (i) fà mọ́ra lọ́wọ́: Wọ́n du ipò alága (ii) ṣe àìfúnni: Wọ́n fi ipò náà dù ú.

dún: mú ariwo jáde: Ó dún bí ìbọn.

dùn: (i) ro ni lára:Ẹsẹ̀ ń dùn mí (ii) wu ni ní jíjẹ: Ọbẹ̀ náà dùn (iii) pọ̀ tó: Iyọ̀ dun ọbẹ̀ náà.



Ee


é: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo pè é, ó dá mi lóhùn

e: (i) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: gbé --->egbé (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo mú igi náà, mo fi àdá gé eè.

è: (i) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: rò ---> èrò (ii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Mo gé e.


Ẹẹ


ẹ́: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo bẹ̀ ẹ́.

ẹ: (i) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kejì ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà: Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ lọ wò ó wá (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kejì tí a fi ń ṣe ìbọ̀wọ̀ fún ní ipò olùwà: Ọ̀gá mi, ṣé ẹ rí owó náà gbà? (iii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kejì ẹ̀yán: Aṣọ ẹ ni mo wọ̀ (iv) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: rù ---> ẹrù (v) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Ó na igi náà sí mi, mo sì bẹ́ ẹ sí méjì ọgbọọgba.

ẹ̀: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹ̀yán: Mo wọ aṣọ ẹ̀ (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kejì ní ipò olùwà: Ẹ̀yin náà, ẹ̀ bá lọ wò ó (iii) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: sìn ---> ẹ̀sìn (iv) atọ́ka ìtẹnumọ́: A bẹ́ ẹ̀ẹ̀ (v) atọ́ka ìyísódì: Ṣẹ́ ẹ̀ lọ? (vi) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kejì tí a fi ń ṣe ìbọ̀wọ̀ fún ni ní ipò olùwà: Ọ̀gá mi, ẹ̀ bá jẹun.


Ff


fá: (i) lo abẹ láti gé kúrò pátápátá: Ó fá irun orí rẹ̀, orí rẹ̀ wá ń dán (ii) fi ọwọ́ gbọ́n dànù: Ó fá ọbẹ̀ inú abọ́ náà kúrò.

fà: (i) jẹ́ kí ó tẹ̀lé ni: Ó fà á jáde kúrò nínú ilé (ii) fí ọwọ́ àti orúnkún rìn: Ọmọ náà ń fà (iii) mú wá sí ọ̀dọ̀ ẹni: Ó fa ọmọ náà mọ́ra (iv) mú dání: Ó fà mí lọ́wọ́ (v) fin: Ó fa tábà náà sí imú (vi) mú kí ó ṣẹlẹ̀: Ó fa kí n jẹ ẹ̀kọ mẹ́ta (vii) yà: Ó fa ìlà sí ojú ìwé rẹ̀ (viii) kí a ní ìfẹ́ àtirí: Ọkàn ìyàwó mi tí ó lọ sí oko ń fà mí (ix) mú wá: Wọ́n fa ìyàwó rẹ̀ fún un (x) pọn: Ó fa omi láti inú kànga (xi) nífẹ̀ẹ́ sí pé kí a jọ wà pọ̀: Ó fà mí, n kò sún mọ́ ọn (xii) láìjá fáfá: Ó ń fà gọ̀lọ̀ (xiii) ṣe bíi rọ́bà: Aṣọ náà ń fà (xiv) kéré sí i: Oówo rẹ̀ ti fà (xv) níní itọ́ gbígbẹ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́: Ó ń fa lala (xvi) tàn: Erèé yìí fà kálẹ̀ (xvii) ṣàìsàn: Ara rẹ̀ fà díẹ̀. Sísùn ni ó ń sùn láti àárọ̀.

fẹ́: (i) wu ni láti ní: Ó ń fẹ́ owó púpọ̀ tí yóò fi kọ́lé (ii) gbé ní ìyàwó: Ọkùnrin náà fẹ́ ẹ wọlé (iii) sọ ọ́ di ọkọ: Obìnrin náà fẹ́ ọkùnrin náà, ó sì di aya rẹ̀ (iv) dàbí: Ó fẹ́ rẹ̀ mí.

fẹ̀: (i) gba àyè sí i: Ó ń fẹ̀ sí i (ii) jókòó bí ọlọ́lá: Ó fẹ̀ sí orí àga.

fi: (i) lò láti ṣe nǹkan: Ó fi ọ̀bẹ gé e (ii) mú sí: Fi ọ̀bẹ sí orí tábìlì. Àwọn ọ̀nà mìíràn tí a fi ń lo ‘fi’ ni ìwọ̀nyí: (ii) Ó fi aṣọ lẹ ẹ̀wù rẹ̀ tí ó ya (iv) Ó ń wá ọ̀nà tí yóò fi jáde (v) Ó fi mí ní ẹ̀pà jẹ (vi) Nígbà tí ó fi ń ṣe tísà ni ó fẹ́ ẹ (vii) Ó lù ú tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi dákú (viii) Hu ìwà tí wọ́n fi lè fẹ́ràn rẹ (ix) Kí lo ṣe tí o fi ṣe é bẹ́ẹ̀ (x) Ó ro gbogbo ohun tí ó fi ṣe é fún mi.

fi: (i) jù: Mo fi apá mi (ii) jù dirodiro: Ó ń fì lórí igi (iii) pọ̀jù: Náírà kan fì í lọ́wọ́ (iv) Jẹ́ kí nǹkan lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún: Ó fi okùn náà sí iwájú àti sí ẹ̀yìn.

fín: (i) tẹ̀ kí ó jáde bí afẹ́fẹ́: Ó fi sheltox fín inú ilé (ii) fẹ́ atẹ́gùn sí: Ó fín iná (iii) jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà: Ẹbọ á fín (iv) dá àrà sí lára: Ó fín igbá.

fó: (i) dá: Ilẹ̀ ti fó (ii) wà ní orí: Ó fó lórí omi.

fò: gbéra kúrò nílẹ̀: Ó fo igi náà.

fọ́: (i) pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ: Ó fọ́ àwo náà sí wẹ́wẹ́ (ii) dùn: Orí ń fọ́ ọmọ náà. Ó ti lo oògùn (iii) kí ó má là: Ojú rẹ̀ ti fọ́ (iv) bàjẹ́: Ó fọ́ iṣẹ́ tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe (v) dẹ ìgbẹ́: Ó ń fọ́ igbó kiri. Ó ń wá ẹran tí yóò fi ṣe ọdún (vi) pò pọ̀ sí inú omi: Ó fọ́ ẹ̀kọ mu (vii) pariwo: Ó ń fọ́ táá (viii) àṣìírí tú: Sàǹgbá fọ́.

fọ̀: (i) fi ọwọ́ gbo nínú omi kí ó lè mọ́: Ó fọ aṣọ (ii) sọ̀rọ̀: Ó fọ̀ sí mi.

fọ́n: (i) tú ká ní ẹyọ ẹyọ: Ó fọ́n erèé sí orí ilẹ̀ (ii) dán: (ẹnu): Ó ń fọ́n ẹnu pé òun lè ṣe é (iii) kán sílẹ̀: Òjò ń fọ́n (iv) wọ́n sí/dà sí: Mo fọ́n omi sí i lára.

fọn: (i) fẹ́ atẹ́gùn sí nínú: Mo fọn fèrè (ii) jẹ́ kí ó jáde: Mo fọn ikun (iii) pariwo: Erin fọn: (iv) tín-ín-rín: Ó fọn.

fọ̀n: (i) mú lo sí ibòmíràn: Mo fọn iná láti lọ dá iná mìíràn (ii) sáré: Ó fọ̀n ọ́n nígbà tí ó gbúròó pé ẹkùn ń bọ̀.

fún: (i) ṣe àìgbà padà: Ó fún mi lówó (ii) funfun: Ó fun bí ẹ̀gbà òwú (iii) kúrò ní ọwọ́ ẹnìkan sí ti ẹlòmìíràn: Ó fún mi lówó (iv) bá ṣe: Mo dé fìlà fún un (v) há: Ó fún gídágídá (vi) nítorí: Ó ń jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ (vii) ní ìwọ̀n àsìkò:: Mo jókòó fún wákàtí méjì (viii) ràn lọ́wọ́: Mo dé fìlà fún un nítorí pé ọwọ́ ń dùn ún, kò lè dé e fúnraarẹ̀.

fun: fẹ́ atẹ́gùn sí nínú: Ó fun fèrè.



Gg


gá: rẹ̀: Ó gá mi.

ga: kí nǹkan máà kúrú: Ọmọ yẹn ga púpọ̀, ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ni ó wọ̀n ní ìjókòó.

gà: ‘ṣí’:  Ó ga agboòrùn rẹ̀.

gán: (i) gé: Ó gán an ní orí (ii) sọ́ lò: Ó gán omi rẹ̀ lò, péèlì omi kan ni ó fi fọ aṣọ mẹ́fà (iii) fi ìdí òkòtó sọ ènìyàn ní ọwọ́: Ó gán an ní mẹ́jọ nígbà tí ó pa á láyò (iv) rán: Ó gán aṣọ rẹ̀ ní ibi tí ó ti ya.

gan: le: Búrẹ́dì yìí ti gan. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti rà á.

gàn: bu ẹnu àtẹ́ lu: Wọ́n ń gàn án fún ìwà pálapàla tí ó wù.

gé: (i) rẹ́ sí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ: Ó gé ẹran náà sí wẹ́wẹ́. (ii) gbá bọ́ọ̀lù kọjá ẹni tàbí kí a yọni ní ẹ̀yọ́: Mo gé e ní ègé ní orí pápá.

gẹ̀: (i) wé: Ó gẹ gèlè (ii) dé: Ó gẹ fìlà (iii) gé: Ó gẹ irun.

gọ́: rẹ̀: Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ tí mo ṣe, ó ti gọ́ mi báyìí.

gọ: sá pamọ́: Ó gọ sí abẹ́ igi.

gọ̀: (i) ṣe aláìgbọ́n: Ó ti gọ̀ púpọ̀ jù, ó lè fi ọwọ́ lásán mú ẹ̀yin iná (ii) yàn: Ó gọ ìbọn.

gún: (i) tí kò wọ́: Igi náà gún (ii) jan ọmọ odó tàbí òkúta mọ́ nǹkan: Ó gún iyán (iii) fi nǹkan bọ̀ ní ara: Ó gún un ní ọ̀bẹ (iv) hù: Ẹyẹ náà gún ìyẹ́ (v) wọ inú: Ẹ̀gún gún un lẹ́sẹ̀.

gùn: (i) tí kò kúrú: Ó gùn púpọ̀. Ó tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́wàá (ii) ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú: Ó gun obìnrin rẹ̀ (iii) lọ sí orí: Ó gun igi (iv) fi jẹ: Ó gun orí oyè (v) ní oyún: Ewúrẹ́ náà ti gùn (vi) bọ́ sí orí: Ó gun ìtẹ́ baba rẹ̀.


GBgb


gbá: (i) gbígbé epo pupa tàbí òróró léná: Ó gbá epo tí ó fi se ọbẹ̀ (ii) ta sí iwájú: Ó gbá bọ́ọ̀lù (iii) jẹ́ kí ó mọ́: Ó gbá ilẹ̀ tí ó dọ̀tí (iv) jàn ní àbàrá: Ó gbá mi létí (v) sáré: Ó gbá tì mí.

gbà: (i) mú fún: Ó gba owó (ii) ọ̀nà ìgbà ṣe nǹkan: Ọ̀nà tí mo gbà yọ nì yẹn (iii) lọ́ràá: Ilẹ̀ yìí gba àgbàdo (iv) fi ọwọ́ sí: Mo gba àbá rẹ̀ wọlé (v) ràn lọ́wọ́: Jọ̀wọ́, gbà mí (vi) rìn sí: Mo gba apá òsì (vii) yọ: Ìkuukùu gba ojú ọjọ́ (viii) ṣẹ́gun: Wọ́n gba ìlú wọn (ix) iye tí nǹkan tó: Kò gba náírà méjì (x) bá lọ: Ó gbé e gba inú ilé (xi) àyè tí nǹkan ní: Inú ilé yìí gba ènìyàn mẹ́wàá (xii) fi nǹkan du ni: Ó gbà á lọ́wọ́ mi (xiii) iye àsìkò tí a lò fún nǹkan: Ó gbà tó oṣù mẹ́rin kí ó tó parí rẹ̀.

gbé: (i) mú: Wárápá gbé e (ii) sí ìdí nǹkan kúrò nílẹ̀: Ó gbé ẹrù náà rù (iii) ọ̀rọ̀ gírámà kan: Níbo ni o gbé rí i?/Mo rí i nílé (iv) sọnù: Ó gbé sí inú igbó (v) ibi tí a ń sùn tí a sì ti ń jí: Ó ń gbé Ìbàdàn (vi) pọ̀ sí i: Ó gbé pẹ́ẹ́ sí i (vii) sẹlẹ̀: Ṣé o rí ibi tí a gbé ṣe àṣìṣe.

gbè: (i) fi ara mọ́: Ó gbè mí (ii) jẹ́ kí ó kó ara jọ sí ojú kan: Ó gbe omi òjò (iii) kọ tẹ̀lé: Ó gbe orin mi.

gbẹ́: (i) họ iwò sí: Ó gbẹ́ ilẹ̀ (iii) jẹ́ kí ó mú lẹ́nu: Ó gbẹ́ lẹ́ẹ̀dì (iii) pariwo láti fi ìgbà tí ó fẹ́ yé hàn: Adìẹ náà ń gbẹ́ (iv) hú (ikọ́): Ó gbẹ́ ikọ́.

gbẹ: láìní omi nínú: Ilẹ̀ náà ti gbẹ.

gbẹ̀: gbìn: Ó gbẹ àgbàdo.

gbin: pa ariwo ìrora: Ó ń gbin nítorí ara tí ó ń ta á.

gbìn: fi bọ ilẹ̀ kí ó tó hù: Ó gbin àgbàdo.

gbó: (i) pa ariwo: Ajá náà ń gbó (ii) dàgbà: Ọkùnrin náà ti gbó. Irun funfun ti yọ ní orí rẹ̀ (iii) tóó jẹ: Àgbàdo mi ti gbó.

gbò: (i) mì: Ó gbo igi náà jìgìjìgì (ii) ní ìfẹ́ àti rí: Àìsí nílé mi gbò ó (iii) dà láàmú: Àìsàn náà ń gbò ó.

gbọ́: (i) kí ọ̀rọ̀ dé etí ẹni: Mo gbọ́ ohun tí o sọ (ii) yé: Mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ (iii) ṣe ohun tí ó yẹ: Mo gbọ́ ti ara mi (iv) rùn sí ní imú: Mo gbọ́ òórùn (v) bọ̀wọ̀ fún: Mo gbọ́ tirẹ̀ (vi) mímọ bí a ṣe ń ṣe nǹkan: Mo gbọ́ ifá.

gbọ̀: lọ́ràá: Ilẹ̀ yìí gbọ ẹ̀fọ́.

gbọ́n: (i) ní iyè nínú: Ọmọ náà gbọ́n púpọ̀. Ọ̀rọ̀ àgbà ló ń jáde lẹ́nu rẹ̀ (ii) bù jáde: Ó gbọ́n omi kúrò nínú ìkòkò.

gbọ̀n: (i) ṣe àìmára dúró: Ó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí ewé ojú omi (ii) yí sí ìhín, yí sí ọ̀hún: Ó gbọn orí láti fi yé mi pé òun kò gba ohun tí mo sọ (iii) sọ òwú òtùtú di èyí tí a fi ń rán aṣọ: Ó gbọn òwú (iv) fi òòlù lu irin gbígbóná: Ó gbọn àdá (v) ta: Ó gbọn òògo (vi) ta dànù: Gbọn ìdọ̀tí kúrò lára ẹ̀wù yìí.

gbún: fi ara kan: Ó fi ẹ̀gbẹ́ gbún mi.

gbun: ṣe aláìgún; Ìlà yìí gbun. Ó rí kọ́lọkọ̀lọ.


Hh


há: (i) ṣe aláìfẹ̀: Ọ̀nà yìí há. Kò gba ènìyàn méjì lẹ́ẹ̀kan náà (ii) gún: Eegun há a ní ọ̀nà ọ̀fun (iii) pín: Ó há ẹran náà fún wọn (iv) fi bọ̀: Ó fi igi há pákó náà ní ibi tí ó ti là sí méjì.

ha: (i) bó: Igi ha mí lára (ii) mú kẹ̀lẹ̀bẹ̀ kúrò: Ó ha ọ̀fun (iii) atọ́ka àmì ìbéèrè: Ìwọ ha ṣe é? (iv) atọ́ka ìtẹnumọ́: Ìwọ á ń kọ́?

hán: dì mú: Mo hán owó tí ó jù sí mi.

han: pariwo: Wọ́n ń han bí i gáte.

hàn: (i) yé ni: Ó hàn pé kò fẹ́ràn mi (ii) tu: Ó han ẹ̀fọ́ (iii) ṣe é rí: Ó hàn sí mi (iv) láìsí tàbí ṣùgbọ́n: Ó hàn pé ó wá.

he: Ó he owó ní ojú ọ̀nà.

hè: fẹ̀: Rọ́bà náà ti hè sí i.

hẹ: (i) jókòó ní etí: Ó fi ìdí hẹ àga (ii) fún ìgbà díẹ̀: Ìjọba fìdí hẹ ẹ́ ni.

hẹ̀: pẹ̀gàn: Ó ṣe hẹ̀ mi.

hẹn: Ìdáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni: Mo bi í pé ṣé ó rí Olú? Ó ní, hẹn

hó: (i) pa ariwo: Wọ́n ń hó hèè bí ìgbà pé ọjà ni wọ́n wà (ii) sí èèpò kúrò lára nǹkan: Ó hó ọsàn (iii) gbóná tó: Omi yìí ti hó. Ẹ jẹ́ kí a fi tẹ ẹ̀bà (iv) ṣe gùdùgùdù: Odò yìí ń hó.

họ: (i) sáré: Ọmọ náà họ nígbà tí ó rí ẹgba (ii) fi eyín ti: Ó họ eegun jẹ (iii) fi èékánná yún: Mo họ ara.

họ̀: pẹ̀gàn: Ó ṣe họ̀ mi.

hú: fà tu: Ó hú igi náà.

hu: (i) mú irun kúrò lára: Ó hu awọ (iii) pa ariwo: Ó hu sí i láti pè é nígbà tí ó dé inú oko.

hù: ‘sọ’: jáde láti inú ilẹ̀: Koríko náà ti hù.

hún: (i) kí ara já ni jẹ: Ara ń hun mí (ii) fi èékánná họ ara: Mo hún ara tí ó ń hún mi.

hun: (i) fi òwú ṣe: Mo hun aṣọ (iii) ìdáhùn bẹ́ẹ̀ ni: Mo ní ṣé ó lọ sí ọjà. Ó sọ pé hun (iii) ìjìyà ẹ̀sẹ̀ kan: Ìkà tí ó ṣe sí mi ni ó ń hun ún yẹn.

hùn: (i) ìmí kanlẹ̀: Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti ń ronú lórí ọ̀rọ̀ náà, ó ṣe hùn (iii) wò-mí-n-wò-ọ́: Ọ̀rọ̀ náà di hùn. Ọ̀rọ̀ pèsì jẹ.


Ii


í: atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú: Ilé la ti í rí i (ii) Ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ àbọ̀: Mo dì í.

i: mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: kú --->ikú (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Mo rí i.

ì: (i) ohun tí kò tí ì ṣẹlẹ̀: Kò ì wá (ii) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: bínú ---> ìbínú (iii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Ó rí i ì.

ín: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Ó mì ín

in: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta àbọ̀: Ó dín in

ìn: (i) atọ́ka ìyísódì: Mi ìn rí i (ii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Ó dín in ìn.




Jj


já: ká: Ó já ọsàn (ii) bọ́ sílẹ̀: Ó já láti orí igi (iii) rùn: Ó ń já fírí (iv) bẹ̀rù: Àya  rẹ̀ ń já (v) tu: Ó ń já ẹ̀fọ́ (vi) gé: Ó já ẹran (vii) kúrò lórí ìṣo: Ewúrẹ́ tí ó ṣo mọ́lẹ̀ ti já (viii) pọ̀ jù: Iyọ̀ ti já ọbẹ̀ tí a sè (ix) dé gbangba: Mo ti já ojú ọ̀nà (x) tó: Déédé ni wọ́n já sí (xi) bá lójijì: Ó já lùmí (xii) kán sílẹ̀: Itọ́ ń já lẹ́nu rẹ̀ (xiii) mọ̀: Ó já irọ́ mi (xiv) parí: Ó wẹ odò náà já.

jà: figa gbága: Wọ́n jà.

jàn: lù: Ó jàn mí ní igi

jẹ́: (i) ṣe: Ó jẹ́ olùkọ́ (ii) búra: Ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ (iii) gbà láyè: Mo jẹ́ kí ó lọ (iv) dáhùn: Mo pè é, ó jẹ́ mi (v) ṣiṣẹ́: Oògùn náà jẹ́ (vi) lè: Bóyá a jẹ́ wá.

jẹ: (i) fi eyín rún kí a sì gbé mì: Ó jẹ búrẹ́dì (ii) ṣe orí ire: Ó jẹ́ tẹ́tẹ́ (iii) nílò àti san padà: Ó jẹ mí lówó (iv) gorí: Ó jẹ oyè: (v) ṣe: Ó ń jẹ fàájì (vi) nà: Ó jẹ ẹgba.

jẹ̀: rìn: Ewúrẹ́ náà ń jẹ̀ káàkiri.

jí: (i) mú ohun tí kì í ṣe tẹni: Ó jí owó mi (ii) dìde nílẹ̀: Ó jí ní orí ibùsùn.

jì: mì síhìn-ín-sọ́hùn-ún: Ó ji oògùn olómi náà kí ó tó mu ún.

jìn: (i) tí kò sí nítòsí: Ilé wa jìn sí tiwọn (ii) wọlẹ̀ gan-an: Ihò náà jìn púpọ̀ (iii) fi gbá: Ó jìn mí lẹ́sẹ̀ láti ẹ̀yìn (iv) fún: Ó fi gbogbo rẹ̀ jìn mí (v) subú: Ó jìn sí kòtò.

jó: (i) fi tapá tẹsẹ̀ dárà sí ìlù: Ó ń jó (ii) gbalẹ̀ sí i: Iná ń jó (iii) ta: Ipín jó o (iv) ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ẹ́: Iná jó o (v) lẹ nǹkan pọ̀: Ó jó irin mọ́ irin (vi) tàn: Àtùpà ń jó (vii) di dúdú tí kò sì ṣe é jẹ mọ́: Oúnjẹ tí ó ṣè sí orí iná ti jó (viii) hún lára: Wèrèpè gbọ̀n jó o.

jò: (i) lu: Abọ́ yẹn ń jò (ii) tàn: Iná ń jò.

jọ: (i) bá mu: Ó jọ mí. A kò yàtọ̀ sí ara wa (ii) jọ ṣe nǹkan pọ̀: Gbogbo wa jọ lọ ni. Kò sí ẹni tí ó dúró sẹ́yìn (iii) ṣe pẹ̀lú ayọ̀: Ọdún dé, ọdún jọ, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa (iv) dàbí: Ó jọ bẹ́ẹ̀.

jọ̀: mú èyí tí kò rí múlọ́múlọ́ kúrò: Ó jọ èlùbọ́

ju: (i) ní kòkòrò: Àgbàdo náà ti ju (ii) sọ: Ó ju òkúta sí i (iii) sẹ́: Ó ju ọwọ́ sí mi (iv) àfi: N kò fẹ́ nǹkan mìíràn ju ìwé (v) fì síhìn-sọ́ùn-ún: Ajá náà ń ju ìrù  (vi) sán: Ó ju igbó (vii) kọjá àsìkò tàbí àyè tí ó tọ́: Ó pẹ́ jù (viii) fi: Ó jù mí lọ́wọ́ sílẹ̀.


Kk


ká: (i) ṣẹ́: Ó ká bébà náà (ii) já: Ó ká ọsàn (iii) mú kúrò níbi tí a sá a sí: Ó ká aṣọ (iv) kó pamọ́: Ó ká ẹní kúrò nílẹ̀ (v) tó fún: Oúnjẹ yìí yóò ká ọdún (vi) kò kọjá agbára ẹni: Ọwọ́ mi ká iṣẹ́ yìí (vii) su ara jọ: Ó ká rúgúdú (viii) yọ: Eyín rẹ̀ ká (ix) kórè: Ó ká ọkà bàbà rẹ̀.

kà: (i) pe àwọn lẹ́tà sínú tàbí sí òde: Ó ka ìwé rẹ̀ (ii) ṣe ní méní-méjì: Ó ka ọsàn rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ mẹ́wàá (iii) sọ gbogbo ohun tó ṣe tí kò dárà: Àjẹ́ náà kà. Ó ní òun ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn jẹ (iv) fún: Ó ka oògùn rẹ̀ lé e lọ́wọ́ (v) lé: Ó gbé e ka orí tábìlì.

kán: (i) yọ díẹ̀díẹ̀: Omi náà ń kán tóó tóó sínú abọ́ (ii) lù: Ó kán mi nígi (iii) dá: Ó kán igi náà sí méjì (iv) láìfẹ́ fàsìkò ṣòfò: Ojú ń kán mi. Mo ti pẹ́.

kan: (i) bàjẹ́: Ọbẹ̀ yìí ti kan. N kò lè jẹ ẹ́ (ii) nọ́ḿbà àkọ́kọ́: Àga kan ni ó gbé wá. Kò pé méjì (iii) tàn ká: Ohùn rẹ̀ gba gbogbo àdúgbò kan (iv) láìsí ìdùnnú: Ilé wọn kan gbínrín.

kàn: (i) fi ọwọ́ lù ko ko ko: Ó kan ilẹ̀kùn kí ó tó ṣí i (ii) dé: Lẹ́yìn Ilé-Ifẹ̀, a kan Iléṣà (iii) tàn kiri: Ìròyìn wa ti kàn (iv) fi lé: Ó fi ògún kan àyà (v) tọ́ sí ni: Èmi ni ó kàn (vi) ṣe láìnídìí: Ó kàn gbá a létí ni láìṣẹ̀ ẹ́.

ké: (i) pariwo: Ó ké (ii) pè: Ó ké sí mi.

kẹ́: (i) tọ́jú: Ó kẹ́ mi (ii) fi í sí ipò tí a ti lè yàn án: Ó kẹ́ ìbọn.

kẹ: ohùn agogo: Aago náà ń ró kẹ, kẹ, kẹ.

kẹ̀: (i) bàjẹ́: Ẹran yìí ti kẹ̀. Kò ṣeé jẹ mọ́ (ii) burú sí i: Egbò rẹ̀ ti kẹ̀ (iii) pọ̀ sí i: Iná náà ń kẹ̀ (iv) rinlẹ̀: Ohùn rẹ̀ kẹ̀ (v) ṣe àìgún. Ẹsẹ̀ rẹ̀ kẹ̀.

kí: (i) ṣe ní pẹ̀lẹ́: Ó kí mi (ii) pé: Ó ní kí n wá (iii) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: ilé ---> ilékílé (iv) atọ́ka ìbéèrè: Kí ni o wí?

ki: ṣe aláìlómi púpọ̀: Ọbẹ̀ rẹ̀ ki.

kì: (i) pe oríkì: Ó kì í (ii) mú: Ó ki eku náà mọ́lẹ̀ (iii) mú lọ́kàn le: Ó kì mí láyà (iv) kẹ́: Ó ki ìbọn.

kín: (i) sún mọ́: Ó kín mi gan-an ni ọwọ́ rẹ̀ ṣe tó mi nígbà tí ó na ọwọ́ sí ọ̀dọ̀ mi (ii) atọ́ka ìbéèrè: Kín ni? (iii) wẹ̀ fún: Ó kín mi lẹ̀yìn (iv) fi ọwọ́ sí: Ó kín ọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn.

kó: (i) gbó jù: Ilá yìí ti kó (ii) mú: Ó kó wọn lẹ́rú (iii) palẹ̀ mọ́: Ó kó ẹrù rẹ̀ (iv) lù: Ó kó àtọ̀sí (v) jí: Ó kó owó wọn (vi) yá: Ó kó owó. Ó fi owó náà ra mọ́tò (vii) wọ̀: Ó kó sínú igbó.

kò: (i) pàdé: Ó kò mí lọ́nà (ii) atọ́ka ìyísódì: Olú kò lọ (iii) yí igi inú iná padà: Ó ko iná.

kọ́: (i) mọ: Ó kọ́ ilé (ii) fi kún ìmọ̀: Ó kọ́ ẹ̀kọ́ (iii) là yé: Ó kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ (iv) fi sí ara nǹkan: Ó fi aṣọ rẹ̀ kọ́ igi (v) ṣáájú: Èmi ni ó kọ́ ṣe é tán (vi) atọ́ka ìyísódì: Ìwọ kọ́ ni ó ṣe é (vii) ja iyàn: Wọ́n kọ́ ọ pé àwọn ọkùnrin ni yóò borí obìnrin.

kọ: (i) pariwo: Àkùkọ kọ (ii) dán: Bàtà náà ń kọ (iii) hàn-ń-túrú: Ó kọ ìwé (iv) gé ẹyìn: Ó kọ ọ̀pẹ (v) kó yẹ̀pẹ̀ jọ: Ó kọ ebè (vii) fi ohùn mú ìró dídùn jáde láti ẹnu: Ó kọ orin (viii) yí: Ó kọ ẹ̀gbẹ́ sí mi.

kọ̀: àìṣe nǹkan: Ó kọ̀ láti lọ.

kú: (i) fi ayé sílẹ̀: Ó ti kú (ii) iye tí ó já sí: Owó ọjà mi kú sí náírà mẹ́rin.

ku: lójijì: Ó kàn mí ku.

kù: (i) tí ó lé sílẹ̀: Ó ku mẹ́ta (ii) jọ̀: Ó ku èlùbọ́ (iii) pariwo: Òjò ń kù (iv) kí afẹ́fẹ́ gbé kiri: Eruku ń kù.

kún: dé ẹnu: Ìkòkò náà kún fún omi.

kun: (i) jó: Ó kun igbó (ii) gé sí kéékèèkéé: Ó kun ẹran.

kùn: (i) fi ọ̀dà dárà sí: Ó kun ilé rẹ̀ ní àwọ̀ funfun (ii) jẹ́ kí ó dán: Ó kun bàtà rẹ̀ (iii) ṣe àìsọ̀rọ̀ jákè tàbí kí a máa ké bí oyin: Ó ń kùn (iv) pariwo: Inú rẹ̀ ń kùn (v) sáré: Ó kùn lọ (vi) finá sí: Ó kun ìgbẹ́ (vii) fi pa: Ó kun àtíkè sí ojú (viii) tòògbè tàbí kí a fẹ́ sùn: Orun ń kùn ún.



Ll


lá: (i) fi ahọ́n fá: Ó lá ọbẹ̀ (ii) rí nǹkan ní ojú orun: Ó lá àlá.

là: gé: Ó là á sí méjì  (ii) lówó: Ó là (iii) pín: Ó la ilẹ̀ náà fún wọn (iv) ṣí: Ó la ọwọ́ rẹ̀. Mo sì fi ìwé lé e lọ́wọ́ (v) jẹ́ kí ó sàn: Ó bu omi là á (vi) ojú mọ́: Ọjọ́ ti là (vii) pẹ̀tù sí aáwọ̀: Ó là wọ́n níjà (viii) yọ nínú ewu: Ọlọ́run là á.

lé: (i) sáré tẹ̀lé: Ó lé e wọlé (ii) yọ kúrò: Wọ́n lé e ní ilé-ẹ̀kọ́ (iii) sí orí nǹkan: Mo gbẹ́sẹ̀ lé e (iv) wú: Apá mi lé (v) pọ̀ sí i: Aṣọ mi ti lé ọ̀kan sí i (vi) tò fún títà: Ó lé iṣu (vii) jáde: Oṣù lé.

le: (i) tí kò rọrùn: Iṣẹ́ yìí le (ii) lágbára: Ọtí yìí le (iii) yá: Ara mi le (iv) tí kò rọ̀: Igi yìí le: (v) burú: Ọkùnrin yẹn le.

lè: (i) wọ̀ fún: O lè máa lọ tó bá wù ọ́ (ii) kápá: Mo lè ṣe é. Kò ju agbára mi lọ.

lẹ́: sú: Alẹ́ ti lẹ́.

lẹ: àìlè ṣiṣẹ́: Ó lẹ púpọ̀. Ọwọ́ rẹ̀ kò ran nǹkan kan.

lẹ̀: (i) fi gọ́ọ̀mù mọ́: Ó lẹ ìwé náà mọ́ ara ògiri (ii) tí ó fẹ́lẹ́ tí ó lè lò síhìn-ín lò sọ́hùn-ún: Igi yìí lẹ̀̀. Ó ń mì síbí mì sọ́hùn-ún.

ló: fi ara balẹ̀: Lọ ló fún ẹ̀mí rẹ.

lò: (i) fi ṣe nǹkan: Ó lò ó ní ìlòkulò (ii) tẹ̀: Ó lò sí apá ọ̀tún (iii) bá ní ìbáṣepọ̀: Ó lò ó.

lọ́: (i) gbìn: Ó lọ́ ẹ̀fọ́ (ii) yí sódì: Ó lọ́ ọ lọ́rùn (iii) dùn: Inú ń lọ́ mi (iv) gbóná díẹ̀: Omi náà ti lọ́ (v) yín: Ó lọ́ mi ní èékánná.

lọ: kúrò ní ibi tí a wà: Ó ti Èkó lọ sí Ìbàdàn.

lọ̀: (i) jẹ́ kí ó kúnná: Ó lọ ata (ii) sọ fún ni: Ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ̀ (iii) jẹ́ kí ó dán: Ó lọ àwọn aṣọ rẹ̀ .

lú: pò pọ̀: Ó lù wọ́n mọ́ra.

lu: fi ihò sí lárá: Ó lu etí rẹ̀.

lù: (i) fi ìyà jẹ: Ó lù ú (ii) kó sí: Ó lu ìjàngbọ̀n (iii) fi nǹkan gbá: Ó lu ìlù.

Mm


ḿ: (i) atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ: Mo ḿ bá a lọ (ii) atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú: Mo ḿ bá a lọ lójoojúmọ́.

má: atọ́ka ìyísódì: Má lọ wò ó.

mà: atọ́ka ìtẹnumọ́: Ó má lọ.

mí: jẹ́ kí èmímí jáde: Ó ń mí. Kò tí ì kú.

mì: (i) jẹ́ kí ó kọjá sí inú: Ó mi oògùn oníkóró (ii) tì síhìn-ín sọ́hùn-ún; Ó ń mi igi náà (iii) dà láàmú: Wàhálà náà kò mì mí.

mo: èmi: Mo lọ.

mò: èmi: Mò ń lọ.

mọ́: (i) ṣe àìdọ̀tí: Aṣọ mi mọ́. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ fọ̀ ọ́ ni (ii) lẹ̀: fi owó mọ́ ọn níwájú orí (iii) yọ́nú sí: Inú rẹ̀ mọ́ sí i (iv) kí ilẹ̀ máà sú: Ojú ti mọ́ (v) láìlẹ́bi: Ara rẹ̀ mọ́ (vi) tọ́jú: Ó mọ́ egbò apá rẹ̀ (vii) rí mú: Ilẹ̀ ti mọ́ olè (viii) kábàámọ̀: Ojú rẹ̀ ti mọ́ (ix) fi ọwọ́ sí: Òun nìkan ni ó fi ara mọ́ ohun tí mo sọ (x) dà: Gìdìgìdì kò mọ́là.

mọ: (i) kọ́: Ó mọ ilé (ii) ṣe ẹ̀dá: Ó mọ ìkòkò (ii) tó: Bí mo ṣe mọ nìyí.

mọ̀: (i) yé: Ó mọ ìdáhùn ìbéèrè náà (ii) bá lò pọ̀: Ó mọ ìyàwó rẹ̀.

mú: (i) dì mọ́ ọwọ́: Ó mú un dání (ii) tí kò kú lẹ́nu: Wọ́n lọ ọ̀bẹ náà. Ó mú dáadáa (iii) fà kí nǹkan ṣẹlẹ̀: Ó mú mi wálé (iv) kí nǹkan máa ṣe ènìyàn: Òtútù mú mi (v) gbẹ̀san: Orí mi ti mú un (vi) rà: Èló ni o mú aṣọ yìí? (vii) fi ẹ̀sùn kàn: Ó mú mi lólè (viii) tẹ̀lé: Ó mú mi lọ (ix) fi sí ọwọ́: Ó mú un.

mu: (i) gbé mì: Ó mu omi (ii) fà sí inú kí a sì tu ú jáde: Ó mu sìgá (iii) fà sí ẹnu kí a sì gbé e mì. Ọmọ náà mu ọyàn ìyá rẹ̀ (iv) jẹ: Ikán ti mu igi náà (v) fi lé orí ahọ́n: Ó mu tábà.

mù: sá pamọ́: Ó mù sí abẹ́ igi. Wọ́n wá a, wọn kò rí i.



Nn


ń: (i) atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ: Mo ń lọ síbẹ̀ (ii) atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú: Mo ń lọ síbẹ̀ lójoojúmọ́.

n: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kìíní ẹyọ ní ipò olùwà: N ó lọ.

ná: (i) fi ra nǹkan: Mo ná owó (ii) yọwó: Mo ná ọjà (iii) lọ sí: Mo fẹ́ẹ́ ná ọjà (iv) tà: Mo ń ná ọjà.

nà: (i) lù: Ó nà mí (ii) fà: Ó nà án láti mọ̀ bí ó ti gùn tó (iii) fi tọká sí: Ó na ìwé náà sí i, ó sì gbà á.

ní: (i) ohun tí ó jẹ́ ti ẹni: Ó ní owó (ii) pé: Ó ní òun ń bọ̀ (iii) àyè nǹkan: Ó wà ní ilé (iv) àkójọpọ̀: Ní akọ, ní abo ni Ọlọ́run dá ènìyàn. (v) ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé: Ó ń kà á ní ení èjì.

ni: (i) jẹ́ ti ẹni: Òun ló ni owó yìí (ii) àìbalẹ̀: Ara ń ni mí (iii) atọ́ka awẹ́ gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́: Olú ni ó ṣe é (iv) àgékúrú fún ẹni: Bíná bá jóni tó jó ọmọ ẹni, ara ẹni là á kọ́ọ́ gbọ̀n (v) àwa: Ó rí ni.

nú: kún: Ó fi ọjà títà nú iṣẹ́ tíṣà.

nù: (i) jẹ́ kí ó mọ́: Ó fi aṣọ nu ara ògiri (ii) tí a kò rí: Ó ń wá àgùntàn rẹ̀ tí ó nù (iii) fún ní oúnjẹ: Ó ń nu ọmọ rẹ̀ (iv) mú kúrò: Ó fi aṣọ nu omi ojú rẹ̀



Oo


ó: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ọ̀rọ̀ náà dùn wọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n rò ó jinlẹ̀.

o: mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: gbó: ---> ogbó (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Mo mú ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà, mo bó o jẹ.

ò: ò: mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: ṣeré ---> òṣèré (ii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Mo bò óò.


Ọọ


ọ́: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Mo lọ sí ìdí òrìṣà náà, mo sì bọ ọ́.

ọ: (i) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó fi ọmo ọ̀dọ̀ kan ránṣẹ́, mo sì bọ́ ọ (iii) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: gbọ́n ---> ọgbọ́n.

ọ̀: (i) mọ́fíìmù ìṣẹ̀dá: lẹ ---> ọ̀lẹ (ii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Mó lọ ọ̀ọ̀

ọ́n: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Mo gbé ọmọ tí ó gbé sílẹ̀. Mo pọ̀n ọ́n sí ẹ̀yìn mi.

ọn: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Mo mú ọ̀bẹ náà. Mo pọ́n ọn dáadáa, ó mú gan-an ni.

ọ̀n:  atọ́ka ìtẹnumọ́: Mo pọ́n ọn ọ̀n.   



Pp


pá: láìsí irun: Orí rẹ̀ pá.

pa: (i) jẹ́ kí ó ṣe aláìsí: Ó pa ejò náà (ii) sọ: Ó pa àlọ́ fún wa (iii) ra: Ó fi epo pa ọwọ́ (iv) kí oúnjẹ má sí ní inú: Ebi ń pa mí (v) kí ó rọ̀ léni lórí: Òjò ń pa mí (vi) kí ó ràn léni lórí: Oòrùn ń pa mí (vii) láìsọ̀rọ̀: Wọ́n pa rọ́rọ́ (viii) sọ̀rọ̀: Wọ́n ń pa ariwo (ix) dà láàmú: Ọtí ń pa á (x) ṣèṣe: Ó fi ara pa (xi) jẹ́ kí ọmọ jáde nínú ẹyin: Adìẹ náà ti pa (xii) là: Ó pa obì (xiii) tà: Ó pa owó (xiv) jà: Wọ́n fi ìjà pa ẹẹ́ta (xv) wò sàn: Wọ́n pa ojú ọgbẹ́ náà (xvi) gé: Wọ́n pa ìgbẹ́ (xvii) kú: Wọ́n pa iná (xviii) darí: Wọ́n pa àṣẹ fún un pé kí ó máa lọ (xix) fọ́: Wọ́n pa èkùrọ́.

pé: (i) kó ara jọ: Wọ́n pé (ii) ní: Ó pé òun ń bọ̀ (iii) mọ́fíìmù ìfi gbólóhùn ṣẹ̀dá orúkọ: Ó rò pé òun á wá (iv) láìṣẹ́kù: Ó pé pérépéré (v) mú èrè wá: Iṣẹ́ mi pé.

pè: ní kí ó wá: Wọ́n pè é.

pẹ́: (i) ṣe àìtètè dé: Ó pẹ́: Òun ni ó gbẹ̀yìn dé (ii) yẹ̀: Ó pẹ́ ẹ sílẹ̀ (iii) ṣe àìtètè bàjẹ́: Ó pẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ mi.

pín: (i) là: Ó pín in sí méjì (ii) jẹ́ kí èyí tí ó kan ẹnì kọ̀ọ̀kan dé ọwọ́ rẹ̀: Ó pín in fún wọn.

pin: tí kò kọjá sí ibì kankan mọ́: Ọ̀nà dórí ọ̀pẹ pin.

pó: oríṣìí ariwo kan: Ẹnu mi ró pó.

pò: yí mọ́ ara: Ó bu mílíìkì sínú tíì, ó pò méjèèjì pọ̀.

pọ́: (i) fẹ́ atẹ́gùn sí: Ó pọ́ táyà (ii) sún ara kì: Ó pọ́ wọlé (iii) kó ìdọ̀tí jáde: Ó pọ́ ìfun ẹran.

pọ̀: (i) ṣe àìmọ níwọ̀n: Wọ́n pọ̀ gan-an ni (ii) bì: Ó pọ oúnjẹ tí ó jẹ́ (iii) tí kò wọ́n: Iṣu pọ̀ lọ́jà lónìí.

pọ́n: (i) yìn: Nítorí pé ó pọ́n ọn ni ó ṣe fún un lówó (ii) pupa: Ojú rẹ̀ pọ́n (iii) lọ̀: Ó pọ́n àdá rẹ̀ (vi) fi ewé yí: Ó ń pọ́n mọ́ínmọ́ín (v) dọ̀tí: Aṣọ rẹ̀ pọ́n (vi) ṣe àìlówó lọ́wọ́: Ojú ń pọ́n ọn.

pọn: (i) sè: Ó pọn ọtí (ii) fi abọ́ tàbí korobá gbé omi: Ó pọn omi.

pọ̀n: (i) gbé sí ẹ̀yìn: Ó pọn ọmọ rẹ̀ (ii) gbéra lọ: Wọ́n mú ọ̀nà pọ̀n.



Rr


rá: (i) fi ṣe àwátì: Owó tí ó fi silẹ̀ ti rá. Kò rí i mọ́ (ii) fà: Ó rá wọ abẹ́ ìràwé lọ.

ra: (i) pa: Ó fi epo pa ara (ii) so: Ó ra okùn wé e (Ó so ó ní okùn).

rà: (i) bàjẹ́: Ẹran yìí ti rà. Kò ṣe é jẹ mọ́ (ii) gba nǹkan kí á sì sanwó fún un: Ó ra bàtà náà ní náírà mẹ́wàá.

rán: (i) fi òwú hun pọ̀: Ó rán aṣọ náà (ii) ní kí a bá ni ṣe nǹkan: Ó rán an níṣẹ́ (iii) kí ibi tí ó ti san tẹ̀lẹ̀ tún máa dun ni láìṣe pé a tún fi pa: Ẹsẹ̀ tí mo fi pa ní ọdún tí ó kọjá tí ó ti san tún ń rán mi (iv) kéré: Ọmọ yìí rán púpọ̀ jù fún ọjọ́ orí rẹ̀ (v) fara dà: Ó fàyà rán an.

ran: (i) sọ òwú ètùtù di èyí tí a fi ń ránṣọ: Ó ran òwú (ii) jó gan-an: Ó ń ran lójú agbo.

ràn: (i) kó bá: Ó kó ikọ́ ràn mí (ii) bá ṣe: Ó ràn mí lẹ́rù (iii) tàn: Oòrùn ń ràn (iv) jó: Igi tí a kó síná ti ràn (v) tàn ká: Àìsàn yìí ti ń ràn (vi) kápá: Ọwọ́ mi ràn án. Mo lè nà án dáadáa. (vii) fà: Ìgbín ràn wọ inú igbó lọ.

ré: mú kúrò: Ó ré aṣọ kúrò lórí ìkọ́ (ii) Ọsàn náà ré láti orí igi (iii) bù díẹ̀ kúrò: Ó ré omi náà lórí (iv) gé: mo ré èékánná mi (v) gbé bú: Ó fi í ré (vi) mú: Tákúté náà ré mọ́ eku ńlá kan (vii) kúrò: Ikú ré lórí mi.

re: (i) ṣe àìní: Igi náà re ewé (ii) yájú: Ọmọ náà re jù (iii) já: Ó re ata.

rè: (i) lọ: Níbo lo rè? (ii) nì yí: Òun rè é.

rẹ́: (i) fẹ́ràn ara: Wọ́n rẹ́ (ii) gé: Wọ́n rẹ́ ẹran náà sí wẹ́wẹ́.

rẹ: (i) fi sínú omi kí ó lè rọ̀: Wọ́n rẹ aṣọ náà (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹnì kejì ẹyọ tí ó jẹ́ ẹ̀yán: Aṣọ rẹ nì yí.

rẹ̀: (i) ṣe àìlókun: Mo ti ṣiṣẹ́ púpọ̀. Ó ti rẹ̀ mí (ii) pọ̀ sí i: Wọ́n bí sí i, wọ́n rẹ̀ sí i (iii) wọ́ sílẹ̀: Ewé igi náà rẹ̀ (iv) pupa: Òdòdò náà rẹ̀ dòdò (v) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹnì kejì ẹyọ tí ó jẹ́ ẹ̀yán: Aṣọ rẹ̀ nì yí.

rí: (i) fi ojú kàn: Ó rí mi (ii) jẹ: Ó rí èrè lórí ọjà (iii) jọ: Báwo ni ó ṣe rí?  (Kí ni ó jọ?) (iv) tẹ́lẹ̀: Ó lọ sí ibẹ̀ rí.

ri: jìn sí ìsàlẹ̀: Ilẹ̀ náà ri.

rì: lọ sí ìsàlẹ̀ omi: Ọkọ̀ náà rì.

rín: fi hàn pé inú ẹni dùn: Ó rín ẹ̀rín.

rin: (i) ní omi nínú: Iyọ̀ náà rin (ii) pọ̀: Òjò náà rin ilẹ̀ (iii) fi irin ha: Ó rin gaàrí.

rìn: (i) kí a máa gbé ẹsẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan kí a sì máa sún sí iwájú tàbí ẹ̀yìn: Ó rìn wálé (ii) fi ọwọ́ tọ́: Ó rìn mí ní abíyá (iii) tẹ̀: Ó rìn mí mọ́lẹ̀ (iv) fẹ́ jẹ́ kí ènìyàn bì: Ó rìn mí láyà.

ró: (i) ọ̀rọ̀ mìíràn fún ‘nàró’: Ó ró sí iwájú ọ̀gá rẹ̀ (ii) dúró: Ó ró dè mí.

ro: (i) dùn: Ẹsẹ̀ ń ro mí (ii) gé: Ó ro oko (iii) kán: Ó ń ro sí inú abọ́ (iv) le: Òní ro fún Ọlá (v) ní ìfẹ́ láti rí: Ojú ń ro mí nítorí Adé.

rò: (i) kí ọkàn wà lára nǹkan: Ó ro inú lé e lórí (ii) pò pọ̀: Ó ro ọbẹ̀ ní orí iná (iii) sọ: Ó ro ẹjọ́ fún un (iv) sè: Ó ro ẹ̀fọ́.

rọ́: (i) sọ: Ó rọ́ àlá (ii) fi pa: Ó fi ẹsẹ̀ rọ́ (iii) yàn: Ó rọ́ àgbá (iv) dún: Àga yìí ń rọ́ kẹ́kẹ́ (v) tì: Ó rọ́ mọ́tò náà sí ojú ọ̀nà (vi) yi: Okùn yìí rọ́ (vii) ṣakọ: Ọmọkùnrin náà ń rọ́ (viii) kí nǹkan kúnná kí ó sì máa fà dọ̀ọ̀: Iyán yìí rọ́ (ix) jọ rìn pọ̀: Wọ́n rọ́ lọ.

rọ: (i) gbẹ: Ewé yìí ti rọ (ii) díjú: Ọ̀nà tí ó rọ ni o gbà (iii) ṣe: Ó rọ ọkọ́ (iv) tí kò lè lò dáadáa: Ẹsẹ̀ rẹ̀ kan rọ (v) dà: Ó rọ omi sí inú ìgò.

rọ̀: (i) bẹ́ sílẹ̀: Òjó rọ̀: (ii) dẹ̀: Ọsàn náà rọ̀ (iii) ṣìpẹ̀ fún: Ó rọ̀ ọ́ pé kí ó má lọ (iv) kí ó má le: Ajá yìí rọ̀ (v) da orí kodò: Ọ̀bọ náà rọ̀ lórí igi (vi) kí ọtí kúrò lójú ẹni: Ojú rẹ̀ ti rọ̀ (vii) kí ènìyàn máà bínú mọ́: Inú rẹ̀ ti rọ̀ (viii) ilẹ̀ ń sú lọ: Ọjọ́ ti rọ̀ (ix) kí a mú àwọn ohun tí a fẹ́: Ó ń sà, ó ń rọ̀ (x) gbé sí ẹ̀gbẹ́: Ó rọ ọmọ rẹ̀.

rú: (i) yọ: Ewé náà ń rú bọ̀ (ii) yí papọ̀: Ó rú omi (iii) dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀: Ó rú ìlú (iv) tẹ̀ lójú: Ó rú òfin (v) kò: Ó rú iná sí oúnjẹ náà (vi) lọ sókè: Èéfín ń rú (vii) ṣe: Ó rú ẹbọ (viii) rọ: Ó rú ọkọ́ (ix) wọ̀: Ó rú sí aṣọ (x) lé jáde: Ó rú igbó kí ó lè rí ẹran pa.

ru: (i) sọ: Omi náà ń ru (ii) sú: Òrú ru (iii) bínú: Inú rẹ̀ ru (iv) yọ ìfòófòó lójú: Ọṣẹ náà ń ru.


rù: (i) ṣe aláìsanra: Ó rù (ii) gbé: Ó ru ẹrù.

rún: (i) di wẹ́wẹ́: Àwo náà rún (ii) jẹ lẹ́nu: Ó rún obì (iii) ṣiṣẹ́ lára: Ó rún awọ (iv) yí padà: Ó rún ara lórí ẹní.

run: (i) dùn: Inú ń run mí (ii) kú tán pátápátá: Ilé wọn ti run (iii) bàjẹ́: Ó run ìlú.

rùn: (i) já fíkán: Ó ń rùn: (ii) fi òkèlè bà: Ó ń run ọbẹ̀ (iii) fi gbo ẹnu: Ó ń run pákò.


SS


sá: (i) jẹ́ kí ó gbẹ: Ó sá aṣọ (ii) fi eré gé e: Ó sá fún un.

sà: (i) kí a pe ni ní orúkọ tí a fi ń sakọ: Wọ́n sà á (ii) múra: Ó sa gbogbo agbára rẹ̀ (iii) ṣe: Ó sa oògùn (iv) fa ìlà ìdámọ̀ sí lára: Mo sà á lámì (v) baatisí: Mo sà á lámì (vi) atọ́ka ìbọ̀wọ̀fún: Mo dúpẹ́ sà.

san: (i) fún ni: Ó san owó rẹ̀ (ii) jiná: Egbò rẹ̀ ti san (iii) ṣe é padà: Ó san oore (iv) tóbi: Ó san ara.

sàn: (i) kí ara yá: Ó ti sàn fún un (ii) dára: Ó sàn jù mí lọ (iii) yí padà sí rere: Ó ń sàn lọ.

sé: (i) dí: Wọ́n sé fèrèsé (ii) ṣe aláìbọ́ sí ojú nǹkan: Òkúta tó jù sé ojú ihò náà.

sè: kí a gbé lé iná kí a sì jẹ́ kí ó jiná: Ó se ọbẹ̀ ilá.

sẹ́: (i) kọ̀ sílẹ̀: Ó sẹ́ mi lójú gbogbo ayé (ii) jọ̀: Ó sẹ́ ògì (iii) atọ́ka ìtẹnumọ́: Èmi ní sẹ́.

sẹ̀: (i) tú jáde: Ẹ̀jẹ̀ ń sẹ̀ ní ara rẹ̀ (ii) wáyé: Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sẹ̀ (ii) fi gbá: Ó sẹ orí mọ́ Adé.

sí: (i) ọ̀rọ̀-atọ́kùn tí ó tọ́ka sí ibi tí a ń lọ. Ó lọ sí Èkó (ii) wà: Kò sí ní ibẹ̀.

sì: ọ̀rọ̀-asopọ̀: Ó rà á, ó sì jẹ ẹ́.

sín: (i) ti atẹ́gùn jáde ní imú lójijì bí ẹni wúkọ́: Ó sín (ii) pa: Ó sín èkùrọ́ (iii) bọ̀: Ó fi òwú sín ìlẹ̀kẹ̀.

sin: (i) bò mọ́lẹ̀: Wọ́n sin òkú wọn (ii) pamọ́: Ó fara sin.

sìn: bọ: Wọ́n sin Olúwa (ii) bá lọ: Ó sìn ín lọ sí ibẹ̀ (iii) fi fún ní ìgbéyàwó: Ó sin ọmọ rẹ̀ fún ọkọ (iv) tọ́jú: Ó ń sin adìyẹ (v) kí a sọ̀rọ̀ àìdáa sí ènìyàn: Ẹnu kò sìn lára rẹ̀ (vi) ṣiṣẹ́ fún: Ó sìn ín fún ọdún mẹ́fà (vii) bèèrè fún: Ó sìn ín ní owó.

só: ba afẹ́fẹ́ jẹ́: Nígbà tí ó só, gbogbo ènìyàn fi ọwọ́ bo imú kí wọn má baà gbọ́ òórùn.

so: (i) ta ní kókó: Ó so igi náà pọ̀ (ii) yọ ọmọ: Ọsàn náà so èso púpọ̀ (iii) kí a ta okùn mọ́ ọrùn kí a fi kọ́ igi kí a lè pa ara ẹni: Ikú àtọ̀run wá kọ́ ni ó kú, síso ni ó so (iv) ní kókó lára: Ara rẹ̀ so.

sọ: (i) yọ jáde: Igi náà sọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ (ii) fọ̀: Ó sọ ọ̀rọ̀ (iii) fi gbá: Ó fi ẹnu sọ igi (iv) jù: Mo sọ ọ́ sí inú abọ́ (v) rán papọ̀: Ó sọ igbá (vi) gbẹ́: Ó sọ ilẹ̀.

sọ̀: (i) wá sí ilẹ̀: Ó sọ̀ láti orí òkè (ii) sọ ohun tí ó ń fi àìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn hàn: Àti àárọ̀ ló ti ń sọ̀.

sú: (i) fọ́n nǹkan ká ní ète àtijẹ́ kí ó lè hù: Ó sú èso ẹ̀fọ́ (ii) dá lágara: Ó sú mi (iii) yọ: Ewé oko sú (iv) sẹ́gìíìrì: Ara mi sú.

sún: (i) kí a mú kí nǹkan kúrò ní ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀: (Ó sún un sí ọ̀dọ̀ mi (ii) gún: Ẹ̀gún sún mi lẹ́sẹ̀.

sun: (i) fi iná jó kí ó lè jiná. Ó sun ẹran náà (ii) tú jáde: Omi ń sun láti inú àpáta.

sùn: (i) pa ojú dé kí oorun mú ni lọ: Ó sùn lé orí ibùsùn (ii) fi ojú dá ọ̀gangan ibi tí ohun tí a fẹ́ sọ nǹkan lù wà: Ó sùn ún dáadáa kí òkúta rẹ̀ lè ba á.


Ṣṣ


ṣá: (i) gé: Ó ṣá a ní ọgbẹ́ (ii) fa ìlà: Ó ṣá kẹ́kẹ́ (iii) tàn: Ó ṣá iná (iii) kí àwọ̀ ṣì: Aṣọ yìí ti ṣá (v) tí kò ṣeé gbọ́kàn lé: Mo fèsì kan ṣá (vi) tí kò lè mú èso púpọ̀ jáde: Ilẹ̀ yìí ti ṣá.

ṣà: mú: Mo ṣà wọ́n nílẹ̀.

ṣán: (i) gé: Mo ṣán igbó (ii) rẹ́: Ó fi símẹ́ńtì ṣán ògiri (iii) jù síbí, jù sọ́hùn-ún: Ó ṣán apá (iv) bù jẹ: Ejò ṣán an (v) sọ mọ́: Ó gbé e ṣánlẹ̀.

ṣàn: (i) wọ́ láti ibìkan lọ sí ibòmíràn: Omi náà ń ṣàn lọ (ii) fọ ara láìsí ọṣẹ: Ó ṣan ara (iii) fọ ọṣẹ kúrò lára: Ó ṣan aṣọ (iv) tí kò ki: Ọbẹ̀ yìí ṣàn.

ṣé: atọ́ka ìbéèrè: Ṣé Olú lọ?

ṣe: (i) ṣẹ̀dá nǹkan: Ó ṣe àpótí (ii) sọ dà: Ó ṣe é ní òfin (iii) tí a lè lò fún nǹkan: Awọ yìí ṣeé ṣe bàtà (iv) atọ́ka ìtẹnumọ́: Ṣe ni mo jẹ ẹ́ (v) bá mu: Ó ṣe wẹ́kú (vi) sọ: Ó ṣe é ní pẹ̀lẹ́.

ṣẹ́: (i) dá: Ó ṣẹ́ igi náà (ii) ká: Mo ṣẹ́ aṣọ náà sí méjì (iii) fi ewé bo: Ó ṣẹ́ ilé náà (iv) àjùmọ̀rìn nǹkan tí ó pọ̀: Ikán ṣẹ́ láti ibẹ̀ (v) ṣe àìlówó lọ́wọ́: Ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ẹ.

ṣẹ: di òótọ́: Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.

ṣẹ̀: (i) dá ọ̀ràn: Ó ṣẹ̀ sí òfin ìlú wọn (ii) wá láti ibìkan: Ifẹ̀ ni a ti ṣẹ̀ (iii) kí nǹkan tí kò dára wáyé: Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ẹ́ (iv) bẹ́ sílẹ̀: Iná ṣẹ̀ (v) gbé: Ó fi orí ṣẹ ẹrù náà.

ṣí: (i) rò pọ̀: Ó ṣí owó (ii) tí kò sí ní pípadé: Ó ṣí ilẹ̀kùn (iii) rà: Ó ṣíyán (iv) jẹ́ kí ó máa lọ: Ó ṣí ọkọ̀ (v) bẹ̀rẹ̀: Ó ṣígun (vi) kúrò: Ó ṣí lọ sí Èkó

ṣì: (i) ṣe àṣìṣe: Ó ṣi ìṣirò méjì (ii) tí kò tí ì dáwọ́ rẹ̀ dúró: Ó ṣì ń lọ sí ibẹ̀ (iii) tí kò tuntun mọ́: Àwọ̀ aṣọ náà ti ṣì (iv) tí ara rẹ̀ kò yá gágá: Ojú rẹ̀ ṣì.

ṣò: tóbi jù: Ṣòkòtò yìí ṣò mí.

ṣọ́: dáàbò bò: Ọlọ́dẹ ń ṣọ́ ilé náà.

ṣú: (i) di dúdú: Ilẹ̀ ti ṣú (ii) fẹ́ẹ́ rọ̀: Òjò ti ṣú (iii) ṣe àìmoore: Ó fi ibi ṣú u (iv) fi èébú san èébú: Ó ṣú mi lóhùn.

ṣu: yàgbẹ́: Ó lọ ṣu.

ṣù: (i) ṣe rìbìtì: Ó ṣu ẹ̀bà (ii) pọ́n: Ó ṣu ẹ̀kọ (iii) pé jọ lé lórí: Àwọn oyin ṣù bò ó.


Tt


ta: (i) yọ síta: Eyín rẹ̀ ta (ii) fi nǹkan tí ó lóró gún lára: Oyin ta á (iii) atọ́ka àmì ìbéèrè: Ta nìyẹn? (iv) yàn: Ó ta ìbọn (v) gbá: Eṣin ta á nípàá (vi) fọ́: Mo ta ifọ̀n tí ó lé sí mi lára (vii) wọ́n sí: Ó ta epo sí mi lára (viii) so mọ́ nǹkan: Ó ta okùn (ix) sá sí iwájú: Ó ta kéré (x) ṣẹlẹ̀ sí lójijì: Ó ta gìrì (xi) jó: Atá ta mí lẹ́nu (xii) ṣe eré: Wọ́n ta ayò (xiii) yọmọ: Iṣu yìí ta (xiv) rùn: Ó ń ta sánsán (xv) pariwo: Òkìkí ta (xvi) yọ: Oòrùn ta (xvii) fẹ́ jiná: Àgbàdo tí a sun yìí ń ta pàrà (xviii) ṣe àìlówó: Òṣí ta á (xix) dùn: Orí ń ta mí.

tà: fún ènìyàn ní nǹkan kí a sì gba owó rẹ̀: Ó ta ọjà fún mi.

tan: jẹ́ ará ilé: Wọ́n tan.

tàn: (i) kí a má lè lọ sí ibì kankan mọ́: Ó ti tàn sí Èkó (ii) jẹ́ kí ó wáyé: Iná tàn (iii) ṣe àìṣòótọ́: Ó tàn mí.

te: kó jọ ní méní méjì: Ó te é jọ.

tẹ́: (i) dá ojú tì: Ó ti tẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yẹn (ii) nà sílẹ̀: Ó tẹ́ ẹní (iii) tí kò ní adùn: Oúnjẹ yìí ti tẹ́ (iv) ṣe pẹrẹsẹ: Ilẹ̀ náà tẹ́.

tẹ̀: (i) gbẹ́sẹ̀ lé: Ó tẹ̀ ẹ́ (ii) ṣe àìtọ́: Ó tẹ̀ (iii) bẹ̀rẹ̀ gún: Ó tẹ iyán (iv) bá sọ̀rọ̀: Wọ́n ń tẹ̀ (v) fi ẹ̀rọ hàn-ǹ-túrú: Ó te ìwé (vi) sè: Ó tẹ ẹ̀bà (vii) rí mú: Ọwọ́ ti tẹ̀ ẹ́ (viii) fi ẹsẹ̀ rìn lórí: Ó ń tẹ ilẹ̀ jẹ́jẹ́ (ix) jìn: Abọ́ yìí tẹ̀ sí inú (x) múra sílẹ̀ láti bímọ: Òbí tẹ̀ ẹ́ (xi) fi kọrin: Ó ń tẹ dùùrù.

tí: (i) ṣe àìtitun: Aṣọ náà ti tí (ii) lù: Ó tí mi nígi (iii) atọ́ka awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe: Aṣọ tí mo rà nìyí.

ti: (i) ha: Ó fi èékánná ti í jẹ (ii) atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán: Ó ti lọ (iii) atọ́ka ìbéèrè: Tìrẹ ti jẹ́? (iv) orísun: Ó ti Èkó lọ sí Ìbàdàn (v) tí ó jẹ́ tẹni: Aṣọ ti èmi.

tì: (i) wà nítòsí: Ilé wa ti tirẹ̀ (ii) rárá: Ó tì (iii) sún sí iwájú: Ó ti mọ́tò náà (iv) padé: Ó ti ilẹ̀kùn (v) sọ di yẹpẹrẹ: Ojú tì í.

tin: ṣe aláìsanra: Ó tin lápá tin lẹ́sẹ̀.

tó: (i) ṣe wẹ́kú: Ọbẹ̀ yìí tó mií jẹun (ii) bí ìwọ̀n kan náà: Ó ga tó mi (iii) àròpọ̀ nǹkan: Ó tó aṣọ  mẹ́ta tí ó rà (iv) yẹ tàbí kí ó tọ́ sí: Aṣọ náà tó náírà mẹ́wàá (v) atọ́ka ìtẹnumọ́: Ojú mi rí tó (vi) lè fi kàn: Ọwọ́ mi tó ìwé náà.

tò: (i) wà ní orí ìlà: Wọ́n tò (ii) kó jọ pọ̀ ní ẹsẹẹsẹ: Ó tò wọ́n.

tọ́: (i) pẹ́ẹ́ bàjẹ́: Bàtà yìí tọ́. Ọdún kẹwàá tí mo ti ń lò ó nì yí (ii) gún: Ọ̀pá ìbọn náà tọ́ (iii) wá ní ìjà: Ó tọ́ mi (iv) bá mu: Ọ̀rọ̀ tí ó sọ tọ́ (v) kọ́ tàbí kí a gbé lọ́dọ̀: Ó tọ́ mi (vi) bá ṣeré: Ó ń tọ́ mi kí n lè dá sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí kí n lè bá a ṣeré (vii) bù nínú: Ó tọ́ ọbẹ̀ sí inú àwo (viii) já ní ọ̀kọ̀ọ̀kan: Ó tọ́ ẹ̀fọ́ (ix) fi ọwọ́ kàn: Ó tọ́ mi (x) yẹ kí ó jẹ́ tẹni: Ó tọ́ sí mi.

tọ: (i) fò: Ó tọ sókè (ii) jẹ: Ìyà tọ lé e.

tọ̀: (i) tẹ̀lé: Ó tọ̀ mí lẹ́yìn (ii) ṣẹ̀yọ́: Ó ń tọ̀.

tú: (i) yọ kúrò nínú ìdè: Ó tú u sílẹ̀ (ii) dà: Ó tú omi sí i (iii) sọ: Ó tú àṣíírí mi (iv) sáré kúrò ní ibi kan: Ojà tú (v) fọ́: Eéwo mi ti tú (vi) rọ̀ kí ó sì dára láti jẹ lẹ́nu: Iṣu náà ń tú (vii) mú kúrò: Ó tú iṣu lórí iná.

tu: (i) bu itọ́ sí: Ejò náà tu sí i lójú (ii) sáré: Ó tu nígbà tí ó rí ejò (iii) fà yọ:  Ó tu koríko (iv) sà ní ọ̀kọ̀ọ̀kan: Ó tu wọ́n jọ.

tù: (i) wà: Ó tu ọkọ̀ (ii) rọ̀: Ó tù ú nínú (iii) kí ara yá: Oówo náà ti tù mí.

tún: lẹ́ẹ̀kan sí i: Ó tún lọ sí ibẹ̀.



Uu


ú: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta  ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó rù ú lé orí.

u: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta  ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó dú u ní ọrùn.

ù: atọ́ka ìtẹnumọ́: Ó dù ú ù.

ún: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta  ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó dùn ún.

un: ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ ní ipò àbọ̀: Ó mú un.

ùn: atọ́ka ìtẹnumọ́:Ó fún un ùn.   





Ww


wá: (i) rìn sún mọ́ ọ̀dọ̀ ẹni: Ó wá sí ilé (ii) fẹ́ láti rí ohun tí ó sọnù: Wọ́n ń wá owó náà (iii) gbọ̀n: Ó ń wá rìrì (iv) sè: Ó ń wá oúnjẹ (v) nísisìyìí: Ó wá yé mi (ii) gbẹ́: Ó wa ilẹ̀ (iii) jẹ́ kí ó rìn: Ó wa ọkọ̀ (iv) mú kúrò: Mo wa ráìsì lórí iná (v) mu: Mo wa gaàrí.

wé ‘gẹ̀: Mo wé gèlè mi sí orí.

wẹ́: (i) tí kò sanra: Ó wẹ́: (ii) kí a gún tàbí kí a lọ̀ kí ó máà kúnná: Ó wẹ́ ata (iii) bá ṣeré: Ó wẹ́ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀.

wẹ: kínǹkan le tàbí kí nǹkan náà pọ̀: Ilẹ̀ wẹ.

wẹ̀: (i) fọ̀: Ó wẹ ara rẹ̀ (ii) kẹ̀: Èmi wẹ̀.

wí: (i) sọ: Kí lo wí? (ii) dá: Ó wí èésú.

wì: sun: Ó wi ẹran.

wín: yá: Ó wín mi lówó.

wó: (i) dà lulẹ̀: Ilé náà wó (ii) kú: Erin wó.

wo: (i) kí ara súnkì bí òkúta: Ọmọ náà wo (ii) ṣe àìsùn: Ọmọ náà kò sùn bẹ́ẹ̀ ni kò wo.

wò: (i) fi ojú rí: Ó wò mí (ii) bẹ̀rù: Ó ń wo ìhín wo ọ̀hún (iii) dákẹ́: Ọ̀rọ̀ rẹ̀ di wò mí n wò ọ́ (iv) ṣe àkíyèsí dáadáa: Ó wò ó wò (v) tọ́jú: Ó wò ó sàn (iv) bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́: Ó wo ifá sí ọ̀rọ̀ náà (vii) bọ́: Ó wo ọmọ náà dàgbà (viii) máà jẹ́ kí ó kú: Ọlọ́run wo ọmọ náà.

wọ́: (i) ṣe aláìgún: Igi yìí wọ́ (ii) fà nílẹ̀: Ó wọ́ ọ (iii) fi ọwọ́ àti ìdí rìn: Ó ń wọ́ nílẹ̀ (iv) là bọ́ sí òdì kejì: Ó fi ẹsẹ̀ wọ́ omi kọjá (v) jọ rìn papọ̀: Èrò ń wọ́ nínú ilé wọn (vi) fi pa: Ó fi oògùn wọ́ ọ lára.

wọ̀: (i) jẹ́ ìtẹ́wọ́ gbà: Ó wọ̀ fún mi (ii) kó sí: Ó wọ inú ilé (iii) já bọ́: Èso náà wọ̀ sílẹ̀ (iv) gbé sí ọrùn: Ó wọ ẹ̀wù (v) kó ìdọ̀tí jáde: Mo wọ ìbẹ́pẹ (vi) gbé: Ó wọ̀ sí ilé mi (vii) dé sí ibi tí yóò sùn: Adìyẹ náà ti wọ̀ (viii) padà sí ibi tí ó ti jáde: Oòrùn ti wọ̀ (ix) tà dáadáa: Ajé wọ igbá (x) mọ̀ lára gan-an: Oorun-ún wọ̀ ọ́ lára (xi) dákẹ́: Ó wọ̀ sin (xii) wúwo: Ẹrù náà wọ̀ ọ́ lọ́rùn (xiii) ráyè: Ó rí ibi bá wọ̀ ọ́.

wọ́n: (i) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ẹyọ ní ipò olùwà: Wọ́n lọ (ii) kí ó má pọ̀: Òjò kò rọ̀. Omi wọ́n lọ́dún yìí (iii) mú kúrò: Ó wọ́n aṣọ sọnù ní ara rẹ̀ (iv) já: Ó wọ́n ilẹ̀kùn (v) kán sí: Ó wọ́n omi sí i lára (vi) mú: Ó wọ́n bọ́ọ̀lù (vii) gbà lẹ́nu ọmú: Ọmọ náà ti wọ́n (viii) gbé owó lórí: Ọjà rẹ ti wọ́n jù (ix) fi pa: Ẹsẹ̀ mi wọ́n.

wọn: (i) kán sílẹ̀: Òjò ń wọn (ii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ọ̀pọ̀ ní ipò àbọ̀: Mo rí wọn (iii) ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹni kẹ́ta ọ̀pọ̀ ní ipò olùwà: Wọn kò rí i.

wọ̀n: (i) yẹ bí nǹkan ti tó wò: Ó wọn ara rẹ̀ lórí síkéèlì (ii) yẹ bí nǹkan ti ga tó wò: Ó fi rúlà wọn ara rẹ̀.

wú: (i) gbẹ́: Ó wú ilẹ̀ (i) tóbi sí i: Ara rẹ̀ wú (ii) ṣe ni bí i kí a máa sunkún: Orí rẹ̀ wú (iv) tètè dàgbà: Ó wú ju ọjọ́ orí rẹ̀ lọ (v) gbẹ́: Ó wú ikọ́ (vi) gbàdúrà: Ó wúre.

wu: wà nínú ìjàǹbá: Ewu wu ú.

wù: (i) fẹ́ràn: Ó wù mí (ii) bàjẹ́: Ẹ̀bà yìí ti wù (iii) yọ jáde nínú ilẹ̀: Àgbàdo yìí ti wù.



Yy


yá: (i) tètè: Ó yá mi (ii) fún ènìyàn ní nǹkan tí a ó sì gbà pàdà lọ́wọ́ rẹ̀: Ó yá mi ní owó (iii) gba nǹkan lọ́wọ́ ènìyàn tí a ó sì san padà: Mo yá owó lọ́wọ́ rẹ̀ (iv) àkókò tó: Ó yá kí a lọ (v) rọrùn: Iṣẹ́ yìí yáá ṣe (vi) fi ọwọ́ fa ìjọ̀ngbọ̀n: Ara ikú ń yá a (vii) sàn: Ara mi ti yá (viii) dunnú: Ara rẹ̀ yá gágá (ix) gbà sí ara: Ó yá iná.

ya: (i) gé sí wẹ́wẹ́: Ó ya ìwé (ii) kí nǹkan pọ̀ jù kí ó sì dé ibi tí kì í dé tẹ́lẹ̀: Odò náà ya (iii) gba ẹ̀san: Ó ya oró lára rẹ̀.

yà: (i) kọ ojú sí: Ó yà sí apá òsì (ii) fà: Ó ya àwòràn (iii) fi bí a ṣe jẹ́ hàn: Ó ya ọ̀lẹ (iv) kóòmù: Ó ya irun (v) ré kọjá: Ó bá mi lọ́nà ó sì yà mí (vi) pín sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀: Wọ́n yà wọ́n.

yán: (i) ti afẹ́fẹ́ jáde láti ẹnu: Ó yán hóóó (ii) nà: Ó yán mi lọ́pàá (iii) jù: Ajá náà yán ìrù (iv) àìbalẹ̀ ara: Wọ́n na ọmo mi, ojú mi yán (v) bùjẹ: Ejò yán an.

yan: (i) sun: Wọ́n yan ẹran (ii) rọra máa gbé ẹsẹ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan: Ó ń yan bí olówó.

yàn: (i) rà: Ó yan ẹ̀kọ (ii) sọ dà: Ó yàn mí ní aṣojú rẹ̀ (iii) di àtẹ́wọ́gbà Obì yàn.

yé: (i) kí a mọ ohun tí ẹnìkan ń sọ: Ó yé mi (ii) yín: Adìẹ náà yé ẹyin (iii) dá dúró: Ó yé iṣẹ́ẹ́ sẹ (iv) jọ̀wọ́: Yé, bá mi ṣe é.

yè: ṣe àìkú: Ọmọ náà ti yè.

yẹ: ṣe wẹ́mú tàbí kí ó bá a mu: Ó yẹ ẹ́.

yẹ̀: pẹ́ sílẹ̀ tàbí kí a sún un síwájú: Ó yẹ ìpàdé náà sí ọ̀la.

yí: (i) rìn ní olóbìírípo: Ó ń yí ní ojú kan (ii) pa ojú dà: Ó yí sí ọ̀hún (iii) máa rọra lọ: Ó ń yí lọ (iv) yí: Ó yí rédíò sókè.

yi: le: Ẹran yìí yi púpọ̀.

yín: (i) rọra máa bù: Ó ń yín oúnjẹ jẹ (ii) yí: Ó yín rédíò rẹ̀ sókè (iii) ẹ̀yin: Ó rí i yín (iv) jẹ́ kí ó máa já bọ́ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan: Ó yín àgbàdo (v) gbé sókè: Ó yín imú sí mi.

yin: (i) gé: Ó fi ọ̀bẹ yin etí tábìlì (ii) fi ọgbọ́n béèrè: Ó yin ọ̀rọ̀ gbọ́ lẹ́nu rẹ̀ (iii) rọra jẹ: Ó ń yín in jẹ.

yìn: (i) kan sáárá sí: Wọ́n yìn ín fun oore ńlá tí ó ṣe fún wọn (ii) ta: Ó yin ìbọn.

yó: (i) tí ebi kò pa mọ́: Mo ti jẹun yó (iii) mu àmujù ọtí: Mo ti yó.

yọ́: (i) rọra rìn: Ó ń yọ́ bọ̀ lẹ́yìn mi (ii) fà: Ó yọ ọ́ sí ìta (ii) hù: Iṣu náà ti yọ jáde (iii) kúrò: Ó yọ nínú ewù (v) mú jáde: Àgbàdo yìí ti yọ ọmọ (vi) dá dúró: Wọ́n yọ ọ́ níṣẹ́ (vii) jọ ni lójú: Iṣẹ́ rẹ̀ yọ (viii) ṣú: Ọ̀rọ̀ náà ti yọ ní ẹ̀mí mi.

yọ̀: (i) fi ṣe ẹlẹ́yà: Wọ́n yọ̀ ọ́ (ii) dunnú: Wọ́n ń yọ̀ (iii) kí ẹsẹ̀ wọ́ nílẹ̀: Ó yọ́ ó sì subú (iv) kí: Ó yọ̀ fún un (v) fà dọ̀ọ̀ọ̀: Gọ́ọ̀mù náà ń yọ̀ (vi) mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ: Ẹnu rẹ̀ yọ̀ (vii) hùwà bí ọmọ tí a ti kẹ́ bàjẹ́: Wọ́n fún ọmọ náà ní ogún náírà, ó ní kò tó òun ún jẹun. Ó ń yọ ni.

yún: (i) lọ: Ó yún ibẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta (ii) họ: Ó yún ara (iii) fẹ́ra kù: Ó ti yún.

yùn: gé: Ó fi ayùn yùn ún.

No comments:

Post a Comment