Tí a bá fẹ́ yí gbólóhùn àṣẹ sódì, mọ́ ni a máa ń lò. Wúnrẹn yìí
kan náà ni a máa ń lò láti yí àpólà kókó-gbólóhùn sódì̀. A
máa ń fa fáwèlì mọ́ yìí gùn.
Àfàgùn yìí sì máa ń ní ohùn òkè fún gbólóhùn àṣẹ. Fún
kókó-gbólóhùn, ohǹn ìsàlẹ̀ ni àfàgùn yìí máa ń wà tí
fáwẹ̀lì atọ́ka ìyísódì fúnra rẹ̀ yóò kúrò ní ohùn òkè yóo di
ohùn àárín. Fún àpẹẹrẹ:
Ifẹ̀ Olórí Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
Ìyísódì
Gbólóhùn Àṣẹ Ìyísódì Gbólóhùn Àṣẹ
(1a) Mọ́ọ̀ lọ (b) Máà lọ
Ìyísódì
Àpólà Kókó-gbólóhùn Ìyísódì Àpólà Kókó-gbólóhùn
(2a) Ó lè mọọ̀ lọ (b)
Ó lè máà lọ
Ìyísódì
Gbólóhùn àti Ìyísódì Àpólà Orúkọ
Ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ kìí lo kò tàbí kìí fún
ìyísódì gbólóhùn. A lè fi ìyísódì gbólóhùn nínú olórí-èka-èdè
Yorùbá wé ti Ifẹ̀ báyìí:
Ifẹ̀ Olóri-èka èdè
Yorùbá
Ìyísódì
Gbólóhùn Ìyísódì Gbólóhùn
(3a) Olúù
lọ (b) Olú kò lọ
(4a) Èmi ìí rí i (b) Èmi kìí rí i
Tí a bá fi (3a) wé (3b), a lè fẹ́ sọ pé láti
ara (3b) ni a ti ṣẹ̀dá (3a) nípa pípa kóńsónáǹtì tí ó ṣáájú
atọ́ka ìyísódì jẹ tí àrànmọ́ sì wá wáyé láàrin fáwẹ̀lì rẹ̀
àti fáwẹ̀lì àpólà orúkọ olùwà. Ní ti (4a) àti (4b), a lè fẹ́ẹ́
sọ pé ìpajẹ kóńsónáǹtì atọ́ka ìyísódì nìkan ni ó ṣẹlẹ̀. Tí
a bá wo àwọn àpẹẹrẹ (5)-(7), a ó yí àbá yìí padà.
Ifẹ̀ Olórí
Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
(5a) Ọbẹ̀ẹẹ̀ gbẹ (b)
Ọbẹ̀ kò gbẹ
(6a) Olú ùú ṣé (b)
Olú kìí ṣe é
(7a) Mẹ́ẹ̀ lọ
(b) N kò lọ
(c) Méè ṣé (d)
N kò ṣe é
(e) Ọ́ ọ̀ lọ (f)
O kò lọ
(g) Ó ò ṣé (h)
O kò ṣe é
(i) Á à lọ (j)
A kò lọ
(k) Ẹ́ ẹ̀ lọ (l)
Ẹ kò lọ
(m) Ẹ́ ẹ̀ ṣé (n)
Ẹ kò ṣe é
(o) Ighán àn lọ (p)
Wọn kò lọ
(q) Ighán àn ṣé (r)
Wọn kò ṣe é
Tí a bá wo atọ́ka ìyísódì ní inú
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ àti olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá (6) àti (7), a lè fẹ́
sọ pé a pa kóńsónáǹtì atọ́ka ìyísódì inú olórí ẹ̀ka-èdè jẹ ní
(6) àti (7) bíi ti (4) tí arànmọ́ sì wá ṣẹlẹ̀ láàrin fáwẹ̀lì
olùwà àti ti atọ́ka ìyísódì lati fún wa ní atọ́ka ìyísódì inú
ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀. Ṣùgbọ́n tí a bá wo (5a), a ó rí í wí pé lẹ́yìn
ìpajẹ àti àrànmọ́ yìí, a tún wá rí fáwẹ̀lì kẹ́ta irú àrànmọ́
yìí tí ó ni ohùn ìsàlẹ̀. Àlàyé tí a lè rí ṣe fún eléyìí ni
pé tí a bá fẹ́ ṣe àlàyé ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí ó ń wáyé
nígbà tí a b́á ń ṣẹ̀dá ìyísódì nínú ẹ̀ka-èdè yìí, a
gbọ́dọ̀ wo ìró ohùn tí ó ṣáájú ìyísódì yìí. Ẹ wo àwọn
àpẹẹrẹ tí ó wà ní (8-12).
Ifẹ̀ Olórí
Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
(8a) Ọbẹ̀ ẹẹ̀ gbẹ (b)
Ọbẹ̀ kò gbẹ
(c) Ọlọ́bẹ̀ ẹẹ̀ ghá
(d) Ọlọ́bẹ̀ kò wá
(e) Òjò oò rọ̀ (f)
Òjò kò rọ̀
(9a) Olú ù lọ (b)
Olú kò lọ
(c) Atá à pọ́n (d)
Ata kò pọ́n
(10a) Aláṣọ ọ́ọ̀ gha (b)
Aláṣọ kò wá
(11a) Ọ̀lẹ ẹ̀ wù mí (b)
Ọ̀lẹ kò wù mí
(12a) Òjo òó rọ̀ (b)
Òjò kìí rọ̀
(c) Olè eèé sùn (d)
Olè kì í sùn
(e) Ọmọ́ ọ̀n ọ́n sùn (f)
Ọmọ kìí sùn
Tí a bá wo (8) dé (11), a ó rí í wí pé
yàtọ̀ sí pé ìró pípajẹ àti àrànmọ́ wáyé, ìró ohùn tí ó
ṣáájú atọ́ka ìyísódì ni ó ń sọ irú ẹ̀dá tí irú atọ́ka
ìyísódì bẹ́ẹ̀ yóò ní.. Irú nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni Abraham
(1958:xvii) pè ní magnetized tones.
Ó tún sọ síwájú pé
Tones flunctuate under
the influence of their environment, some succumbing to the influence of words
preceding them, while others are affected by what follow.
Irú àkíyèsí kan náà ni Bamgboṣe (1990: 179)
ṣe nígbà tí ó ń ṣe àláyé sílébù olóhùn òkè. Lára ohun tí ó
sọ ni pé
Nígbà tí olùwà bá
dúró ṣáájú àpólà ìṣe, ìyípadà ohùn tàbí ohùn àti sílébù
máa ń ṣẹlẹ̀ sí sílébù tí ó gbẹ̀yìn olùwà. Òfin tí ó de
ìyípadà yìí ni. … A gbọ́dọ̀ fi
sílébù olóhùn òkè kún ohùn àárín tó gbẹ̀yìn tí ó sì tẹ̀ lé
ohùn òkè …
Irú nǹkan tí ó máa ń ṣẹlẹ sí ìṣẹ̀dá
atọ́ka ì̀yísódì nínú ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ nì yí. Àmì ohùn orí ọ̀rọ̀
tí ó ṣáájú atọ́ka ìyísódì ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ni ó máa ń sọ irú
ohùn tí atọ́ka ìyísódì bẹ́ẹ̀ yóò ní. Ní (8) tí atọ́ka
ìyísódì ẹ̀ka-èdè Ifẹ̀ ti ní àmì ohùn kan náà, atóka
ìyísódì tẹ̀ lé àmi ohùn
ìsàlẹ̀ tí àmì ohùn àárin ṣáájú ní (8a). Ní (8c), ohùn ìsàlẹ̀
tí ohùn òkè ṣáájú ni atọ́ka ìyísódì tẹ̀ lé . Ní (8e), ohùn
ìsàlẹ̀ tí ohùn ìsàlẹ̀ mìíràn ṣáájú ni atọ́ka ìyísódì tẹ̀
lé. Ní (9), Ohùn òkè tí ohùn àárín ṣáájú ni atọ́ka ìyísódì
tẹ̀ lé ní (9a). Ohùn àárín tí ohùn àárín mìíràn ṣáájú (ata)
ni ó ṣáájú atọ́ka ìyísódì ní (9c). Ní (10a), atọ́ka ìyísódì
tẹ̀ lé ohùn àárín tí ohùn òkè ṣáájú. Ní (11), atọ́ka ìyísódì
tẹ̀lé ohùn àárín tí ohùn
àárín mìíràn ṣáájú.
Ní ibi tí a bá ti lo atọ́ka ìyísódì kìí nínú olórí ẹ̀ka-èdè
Yorùbá bíi ti (6b), Ifẹ̀ máa ń lo ẹ̀yà tí ó wà ní (6a) àyàfi:
(13a) nígbà tí atọ́ka
ìyísódì bá tẹ̀ lé ohùn ìsàlẹ̀ tí ohùn ìsàlẹ̀ mìíràn
ṣáájú bíi ti (12a) níbi tí ohùn àárín ti ṣáájú ohùn ìsàlè ti
ó śáájú atọ́ka ìyísódì
(b) nígbà ti atọ́ka
ìyísódì bá tẹ̀ lé ohùn ìsàlẹ̀ tí ohùn àárín ṣáájú bíi ti
(12d), a máa ń fa ohùn ìsàlè. ara olùwà gùn (tí ó jẹ́ olè níbí yìí) tí àfàgùn yìí yóò sì ní ohùn
àárín.
(c) nígbà ti atọ́ka ìyísódì bá tẹ̀ lé ohùn
àárín tí ohùn àárín mìíràn ṣáájú bíi (12f) níbi tí ohùn
òkè tí ó ṣáájú atọ́ka ìyísódì ti yí padà sí àárín.
Ó yẹ kí a mẹ́nu ba ìyísódì arọ́pò-orúkọ
ẹni kẹ́ta tí a kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nizgbà tí a ń sòrọ̀̀ nípa
àwọn àpẹẹrẹ tí ó wà ní (7). Abimbola àti Oyelaran (1975: 42)
dábàá àwọn òfin kan tí a máa ń lò tí a bá fẹ́ pa kóńsónáǹtì
jẹ. Òfin méjì tí wọ́n fún wa fún ìpajẹ kóńsónáǹtì ni:
(14a) Obligatory
deletion of the 3rd sing. Pro. Before kò/kì ‘NEG’, yóò
‘will’ and kì ‘PROBABLE’.
(b) The optional
deletion of the initial segment of a grammatical formative that follows one
formative and precedes another item
Ọkan nínú àwon òfin méjì yìí ni a lè lò
fún wúnrẹ̀n kan. Tí a bá wo (15)
àti (16), a ó rí i pé (14a) ni olórí ẹ̀ka-èdè Yorùbá mú lò nígbà
tí ifẹ̀ mú (14b) lò.
Olórí
Ẹ̀ka-èdè Yorùbá
(15a) *Ó kò lọ (b)
Kò lọ
Ifẹ̀
(16) *Ẹ kò lọ (b)
*Ẹ́ ò lọ (c)
Ẹ̀ ẹ̀ lọ
Ní (15a), òfin (14a) ni a mú lò ní kan-ń-pá
láti fún wa ni (15b). Ní (16a), òfin (14b) ni a mú lò ní kan-ń-pá
láti fún wa ní (16b). Lẹ́yìn èyí ni àrànmọ́ wá wáyé láti fún wa
ní (16c).
Àkójọ
Orúkọ Ìwé
Abimbola, W. and O. Oyelaran (1975), ‘Consonant Elision in Yorùbá’, African Language Studies 16: 37-60.
Abraham, R.C. (1958), Dictionary of Modern Yoruba. London: University of London Press.
Adetugbo, A. (1967), ‘The Yoruba Language in Western
Nigeria: Its Major Dialeect Areas.’ PhD Dissertation, Columbia University.
Adetugbo, A. (1973), ‘The Yoruba language in Yoruba
History’, in Sources of Yoruba History,
edited by S.O. Biobaku, pp. 176-204. Oxford: Clarendon Press.
Adewole, L.O. (1996), ‘Ife Pronouns in Polylectal
Grammar’, Journal of Nigerian Languages
and Literatures2: 56-63.
Arohunmolase, O. (1987), Agbeyewo Idagbasoke Ede ati Yoruba Akoto Yoruba. Ibadan: Onibonoje
Press and Books Industries (NIG) Ltd.
Awobuluyi, O. (1992), ‘Aspects of Contemporary
Standard Yoruba in Dialectological perspective’, in New findings in Yoruba Studies,
edited by A. Isola, pp. 1-79, Ibadan: JF Odunjo Memorial Lecture.
Chambers, J.K. and Peter Trudgill (1980), Dialectology. Cambridge: Cambridge
University Press. Crystal, David (1996), ‘Slip of Mother Tongue’, the Independent on Sunday (January 4
ed.), p. 7.
Doipohyne, Florence (1976), ‘Dialect Differences and
Historical Records in Akan’, Legon
Journal of the Humanities 2: 15-27.
Trudgill, Peter (1984), Dialects, edited by Richard Hudson. London: Routledge.
No comments:
Post a Comment