Friday, 15 May 2015

Èdè Yorùbá ní Ṣókí




 Èdè alóhùn ni èdè Yorùbá. Ìró ohùn mẹ́ta ni ó wà nínú èdè náà. Àwọn ìró ohùn náà ni ìró ohùn òkè (bí àpẹẹrẹ, ìró ohùn tí ó wà lórí “ó wá”), ìró ohùn ìsàlẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, ìró ohùn tí ó wà lórí “kò wẹ̀”) àti ìró ohùn àárín. A kì í lo àmì kankan láti fi ìró ohùn àárín hàn àyàfi ìgbà tí kọ́ńsónáńtì àránmú aṣesílébù bá ní ìró ohùn àárín ni a máa ń lo àmì yìí, “-”, bí àpẹẹrẹ, àmì ohùn àárín ni àwọn fáwẹ́lì inú “ọmọ” ní bẹ́ẹ̀ náà ni “n” tí ó jẹ́ kọ́ńsónáńtì àránmú aṣesílébù inú “gbangba” ṣe ní àmì ohùn àárín.
     
Ìró fáwẹ́lì àránmúpè  márùn-ún ni èdè Yorùbá ní. Àwọn náà ni:
      an, ẹn, in, ọn, un.

Àwọn ìró kọ́ńsónáńtì tí ó wà nínú èdè Yorùbá ni:

      b, d, f, g, gb, h, j, k, l,
      m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ ni a ti yá wọ inú èdè Yorùbá láti inú èdè mìíràn. Àwọn kan jẹ́ àfetíayá (bí àpẹẹrẹ: báíbù, pẹ́ńsù, abbl.), àwọn kan sì jẹ́ àfojúyá (bí àpẹẹrẹ: bíbélì, tábìlì, abbl.). Láti fi ara àwọn ọ̀rọ̀ àyálò mọlé, a lè pín ìṣùpọ̀ kọ́ńsónáńtì inú ọ̀rọ̀ èdè mìíràn níyà (bí àpẹẹrẹ, French – faransé, break – búréèkì, abbl.), a lè dín ìṣùpọ̀ kọ́ńsónáńtì kù sí ẹyọ kan (bí àpẹẹrẹ, station – tésàn), a sì lè fi fáwẹ́lì kún ọ̀rọ̀ tí kọ́ńsónáńtì bá parí rẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, gem – jẹ́ẹ̀mù).
     
Nínú afọ̀ geere, a máa ń pa ìró jẹ (bí àpẹẹrẹ, etí ilé – etílé, àdúrà – àdúà), a máa ń jẹ́ kí àránmọ́ wáyé (bí àpẹẹrẹ, ilé ìwé – iléèwé, ará ọ̀run – arọ́ọ̀run, oní ẹja - ẹlẹ́ja, abbl.) a sì máa ń jẹ́ kí ìyọ́pọ̀ fáwẹ́lì ṣẹlẹ̀ (bí àpẹẹrẹ dá ọpẹ́ – dúpẹ́). Nínú gbogbo ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì wọ̀nyí ni àsúnkì ti lè wáyé (bí àpẹẹrẹ, gbẹ́ odó – gbẹ́dó).
     
Ìhun gbólóhùn tí àyídá kò tíì ṣẹlẹ̀ sí ni olùwà+ọ̀rọ̀-ìṣe+àbọ̀ , bí àpẹẹrẹ, Olú na Adé níbi tí Olú ti jẹ́ olùwà tí nà jẹ́ ọ̀rọ̀-ìṣe tí Adé sì jẹ́ àbọ̀. Ẹ̀yán ni ó máa ń tẹ̀ lé orí nínú awẹ́-gbólóhùn aṣàpèjúwe (bí àpẹẹrẹ “aṣọ tí mo rà” níbi tí “aṣọ” ti jẹ́ orí tí “tí mo rà” sì ń yán an). Bákan náà ọmọ ṣe orí nínú àpólà orúkọ tí kò ní ju ọ̀rọ̀-orúkọ àti ẹ̀yán rẹ̀ lọ (bí àpẹẹrẹ, “ọmọ pupa” níbi tí “pupa” ti ń yán “ọmọ” tí “ọmọ” sì jẹ́ orí nínú àpólà náà).
     
Ọ̀rọ̀-atọ́kùn mẹ́ta ni ó wà nínú èdè Yorùbá. Àwọn náà ni “ti” (tí ó ń fi ibi tí nǹkan ti gbéra (source) hàn, bí àpẹẹrẹ “Mo ti Èkó lọ sí Ìbàdàn”), “sí” (tí ó ń fi àbáyọrí (goal) hàn, bí àpẹẹrẹ “Mo lọ sí Iléṣà”) àti “ní” (tí ó ń fi àyè (location) hàn bí àpẹẹrẹ, “Adé rí Olú ní Ojà”)[1].
     
Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀-ìṣe ni nínú èdè Yorùbá, bí àpẹẹrẹ “Olú lọ kíákíá” àti “Mo ṣe iṣẹ́ rí” níbi tí “kíákíá” àti “rí” ti jẹ́ ọ̀rọ̀-àpọ́nlé[2].
Ìgbóhúnsókè ni ó máa ń ya gbólóhùn àlàyé sọ́tọ̀ sí gbólóhùn ìbéèrè oní-bẹ́ẹ̀-ni-bẹ́ẹ̀-kọ́, “Olú wẹ̀” lè jẹ́ gbólóhùn àlàyé tí a kò bá gbé ohùn sókè lórí fáwẹ́lì “ẹ̀” tí ó parí gbólóhùn yìí ṣùgbọ́n tí a bá gbé ohùn sókè lórí rẹ̀, yóò di gbólóhùn ìbéèrè oní-bẹ́ẹ̀-ni-bẹ́ẹ̀-kọ́.
      
Àwọn atọ́nà wà tí a máa ń lò láti ṣe ìbéèrè nínú gbólóhùn ìbéèrè tí kì í ṣe oní-ni. Àwọn atọ́nà wọ̀nyí lè wà ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin gbólóhùn. Àwọn kan tilẹ̀ gbà pé ó lè wà ní ààrin gbólóhùn pẹ̀lú. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ yàtọ̀ ní ìsàlẹ̀ wọ̀nyí ni ó jẹ́ atọ́nà gbólóhùn ìbéèrè tí kì í ṣe oní-ni.
           
Ṣé Olú lọ?
            Olú lọ bí?
            Olú tíì dé?

Oríṣìí gbólóhùn ìbéèrè oní-ni méjì ni ó wà? Èkínní ni gbólóhùn ìbéèrè oní-ni alápèpadà, èkejì sì ni gbólóhùn ìbéèrè oní-ni aláìlápèpadà. Àpẹẹrẹ gbólóhùn ìbéèrè oní-ni alápèpadà ni (b) ní ìsàlẹ̀ yìí:
     
      (a)  Má fi ọwọ́ kàn án
      (b)  Má fi ọwọ́ kan kí ni?

Àpẹẹrẹ gbólóhùn ìbéèrè oní-ni aláìlápèpadà ni:

            Ta ni ó ra aṣọ?

Bí ìrísí ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ èdè Yorùbá ṣe rí nì yí:
                             
                                          Ipò Olùwà

                     Ẹyọ                                   Ọ̀pọ̀
Ẹni kìíní:      mo (Mo ra iṣu)          a (A ra iṣu)
Ẹni kejì:       o (O ra iṣu)              a ( ra iṣu)
Ẹni kẹ́ta:      ó ([3] ra iṣu)             wọ́n (Wọ́n ra iṣu)
     
                                          Ipò Àbọ̀

                     Ẹyọ                            Ọ̀pọ̀
Ẹni kìíní:      mi (Ó rí mi)              wa (Ó rí wa)
Ẹni kejì:       ọ/ẹ (Ó rí ọ/ẹ)           yín (Ó rí yín)
Ẹni kẹ́ta:      àfàgùn fáwẹ́lì
                  ọ̀rọ̀-ìṣe (Ó rí i)           wọn (Ó rí wọn).
                                         

                                          Ẹ̀yán
                     Ẹyọ                            Ọ̀pọ̀
Ẹni kìíní:      mi (Aṣọ mi)              wa (Aṣọ wa)
Ẹni kejì:       rẹ/ẹ (Aṣọ rẹ/ẹ)         yín (Aṣọ yín)
Ẹni kẹ́ta:      rẹ̀/ẹ̀ (Aṣọ rẹ̀/ẹ̀)         wọn (Aṣọ wọn)

Yorùbá ní ọ̀rọ̀-arọ́pò afarajorúkọ. Ìrísí wọn nì yí:

                  Ẹyọ                            Ọ̀pọ̀
Ẹni kìíní:      èmi (Èmi ni mo rí i)   àwa (Ó rí àwa)
Ẹni kejì:       Ìwọ (Ìwọ ni ó rí i)     ẹ̀yin (Ó rí ẹ̀yin)
Ẹni kẹ́ta:      òun (Ó rí òun náà)     àwọn (Àwọn ni a rí i)

À lè ṣe àtúnpín ọ̀rọ̀-ìṣẹ Yorùbá sí ìsọ̀rí wọ̀nyí: ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ (àfàgùn fáwẹ́lì tí ó gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀-ìṣe tí ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́ tẹ̀ lé ni ó máa ń jẹ́ atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe ọ̀bọ̀rọ́, bí àpẹẹrẹ, “Ó fẹ́ẹ́ lọ, Ó bẹ̀rẹ̀ sí iṣẹ́ẹ́ ṣe, Ó bẹ̀rẹ̀ sí lọ), ọ̀rọ̀-ìṣe aṣàpèjúwe (bí àpẹẹrẹ, “Ọmọ náà ga, Iṣu náà tóbi), ọ̀rọ̀-ìṣe oníbọ̀ (bí àpẹẹrẹ, “Ilẹ̀kùn bàjẹ́,ba ilẹ̀kùn jẹ́), ọ̀rọ̀-ìṣe aláìlẹni (bí àpẹẹrẹ, Ó dára kí á pa àgọ́ mẹ́ta), ọ̀rọ̀-ìṣe àkànmórúkọ (bí àpẹẹrẹ Ó pàdée Dayọ̀), ọ̀rọ̀-ìṣe alápèpadà (bí àpẹẹrẹ, Kọ́bọ̀ ló kù mí kù), ọ̀rọ̀-ìṣe agbẹ̀rún (bí àpẹẹrẹ, Ó pè mí ní Olówó), ọ̀rọ̀-ìṣe aṣokùnfà (bí àpẹẹrẹ, Ó ní òun ń bọ̀) àti ọ̀rọ̀-ìṣe àsínpọ̀ (bí àpẹẹrẹ, Ó gbé ìjòkó wá sí ilé.).
     
Àwọn ọ̀nà tí a fi ń ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ nínú èdè Yorùbá ni nípa lílo àfòmọ́-ìbẹ̀rẹ̀ (bí àpẹẹrẹ, sùn – àìsùn), nípa àpètúnpè ẹlẹ́bẹ (bí àpẹẹrẹ, jẹ - jíjẹ), nípa ṣíṣe àpètúnpè kíkún (bí àpẹẹrẹ, pẹja – pẹjapẹja, ọdún - ọdọọdún, abbl.)
     
Àwọn atọ́ka ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ nínú èdè Yorùbá ni ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ àṣetán (Olú ti lọ), ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ atẹ́rẹrẹ (Olú lọ), àti ibá-ìṣẹ̀lẹ̀ bárakú (Adé máa ń lọ). Àwọn atọ́kà múùdù (ojúṣe) ni ojúṣe àníyàn[4] (Èmi yóò lọ), Ojúṣe wọ̀fún (Dàda lè lọ) àti ojúṣe kàn-ńpá (Adé gbọ́dọ̀ ṣe é).
Àwọn àpẹẹrẹ oríṣìíríṣìí gbólóhùn nínú èdè Yorùbá ni gbólóhù àṣẹ (Mú un wá), gbólóhùn àtẹnumọ́ (Mo ti dé o), gbólóhùn àkíyèsí alátẹnumọ́ (Aṣọ ni mo rà), gbólóhùn oníbọ̀ (Tí ẹ bá dé, ẹ pè mí), gbólóhùn àyísódì (Olú kò lọ) àti gbólóhùn alákànpọ̀ (Adé ra aṣọ ṣùgbọ́n kò rán an).


[1] Àríyànjiyàn sì  wà lórí àwọn wúnrẹn tí a lè pè ní ọ̀rọ̀-atọ́kùn.
[2] Àríyànjiyàn sì  wà lórí àwọn wúnrẹn tí a lè pè ní ọ̀rọ̀-àpọ́nlé.
[3] Gbogbo onímọ̀ gírámà èdè Yorùbá kọ́ nió gbà pé arọ́pò-orúkọ yìí wà nínú èdè Yorùbá.
[4] Àsìkò ọjọ́ iwájú ni àwọn onígírámà kan ń pe eléyìí.

No comments:

Post a Comment